Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all 2260 articles
Browse latest View live

Sacrifice (Ebọ; Etutu)

$
0
0

Sacrifice (Ebọ; Etutu)
Medium: Chinese Bamboo on bond paper

Atelewọ ni o hu’run hèùhèù
Dia fun Mofẹ́ẹ́ní
Tín bẹ láàrín Òsììrí
Tín bẹ láàrín ìpọ́njú
To wá nlọ rèé k’owó lọ’dọ̀o Kìífẹání
Ẹbọ ni wọ́n ní kó ṣe
O gbẹ́bọ, ó rúbọ
Kò pẹ́, kò jìnnà
Ire gbogbo wáá wọlé de tùtúru
Njẹ́ aronipin o m’ọ̀la o
Bí a ò kú, iṣẹ́ ò tán
Aropin o m’ọ̀lá o — Ọ̀wọ́nrín Méjì


Ibeere Toni: laiye ‪#‎Ijohun ati ‪#‎Aye Ode oni

$
0
0

Ojuwo lefi wo asa ila kiko laiye ‪#‎IJOHUN‬ ati
‪#‎AIYE_ISIN‬ …..nje odara kamo ko omo wa nila
bi???

Olojo Ibi Toni

$
0
0

Mo layo lati so fun yin wipe oni ni ojo ibi Alagba Oluwakayode Olamilekan Adekoya Ijeni ti won je okan gboogi ninu ebi Omo Yoruba.
Okan pataki ni won je lara awon majekobaje ilu yi, oloye nla niwon laafin Olumoye. Balogun igbomekun oye ni mo nke si.
OBA lori Ogun, mo ki yin e ku ayo oni, e o se pupo re laye ninu alafia ara ati ibale okan.

Ni oruko Oluwa e o ni ba won na oja warawara nile aye beeni e o si ni dagba yeye, gbogbo ohun rere ti n mu’le aye rorun fun eda ni Eledua yoo fi jinki yin. E o gbo, e o to, e o fewu pari, e o ferigi jobi, e o gbele aye sohun rere bi o ti wa wu ki e pe to laye e o ni f’oju mo saare omo lase Edumare.
Kabiyesi ati awon Oloye ati gbogbo ebi Omo Yoruba Atata pata nileloko nki yin wipe IGBA ODUN, ODUN KAN NI O..

Eeto Owe L’esin Oro 4

$
0
0

Mo ki gbogbo wa kaabo si akotun eeto yin, eeto wa owe l’esin oro. Laakoko, mo dupe lowo Olodumare ti o funwa ni oore-ofe lati tun pade loni, leyin igba ti a dagbere fun eeto ni ose to koja. Moki kabiyesi olumoye ti ilumoye akoko, awon olori, moki awon oloye, gbogbo igbimo aafin ati awon omo’oba l’okunrin ati l’obinrin. Gegebi isee wa, lori eeto yii ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan ti a o si maa fi ko ara wa le’eko. Ni bayii e je ki a kanlu agbaami eeto.

Owe ti a o koko gbe yewo loni loo bayii- TI OJU BA N SE IPIN, A MAA N YO FI HAN OJU NI.
Ti oju ba ni idoti, gbara ti a ba ti yoo tan loju, eyan a fe mo ohun gan-an to n daamu oju re, oju ni yoo fi han lati rii, eyi ni won fi n so wipe b’oju ba n se ipin, aa yo han oju ni. Eyi ni wipe bi oko ba gba eyan, oko naa la o fi gbe e lo si ile iwosan lati toju.
Itumo ijinle; bi eyan ba huwa ibaje kan, won a je ki iru eni bee mo ni kiakia.
Lilo re; ti enikan ba n se nkan ti ko bojumu lawujo, ti a wa n dalekun tabi ti a n je ko yee wipe nkan ti o n se yii kobujumu to, a le pa owe yii fun iru eni bee wipe, bi oju ba n se ipin, a n yoo han ni, ko le mon wipe nkan ti oun nse kodaa.

Owe keji fun toni loo bayii- IGI GOGORO MAA GUNMI L’OJU, LATI OKEERE NI A TIN N LOOO.
ti eyan ba ti ri igi ti o yo sonso to le gun l’oju, lati ookan ni eyan a ti maa yera fun tabi dooji (dodge) re. Eyan o le laju sile ki o ri igi to le se e lese lo’okan, ki o maa yera fun-un, lai se omugo eniyan.
Itumo ijinle; ti eeyan ba n huwa ibaje kan, a gbodo tete je ko mon ko le tete jawo, tori bi ara ile eni ba n nje kokoro to oo dara, ti a o wi fun-un, huruhere re ko ni je ka sun loru.
Lilo re; ti a ba sakiyesi wahala kan ti o seese ki o suyo, ti a wa tete fe wa ona abayo si irufe wahala naa ki o to bee sile ni a le pa owe yii.

Owe keta fun toni lo bayii- AIFI ELE KEBOOSI, NI AI R’ENI BANI JOO.
aifarabale ke boosi ni o je ko dun un jo.
Ti eyan ba wo aarin oja to n korin wipe “iboosi o, iboosi o, iboisi o iboisi o” ki o to mo oun to n sele, awon eero a ti bo o, ti won yoo si maa joo si orin naa paapa. Sugbon ti eyan ba wo aarin oja to ni, “iboooooooosi oooo” awon eyan a tuka lori ere ni, pentuka ni, oro yoo di bo o lo o ya funmi, ki oju maa ribi nii, gbogbo ara lo’ogun re…..ere asapajude nii.
Itumo ijinle; aifarabale, aifogbon se e, aini suuru lo faa, ko si ohun ti a fi suuru o le se, suuru le se okuta jinna, bi eyan ba farabale, bo ba pa eera, yio ri ifun re ko. Pele la n pa amukuru pele. Ohun a feso mu kii baje, ohun ti a ba fipa mu, koko ni le mo nii. Eni to ba ni suuru, ohun gbogbo lo ni.
Eyi tun tumo si wipe ohun gbogbo ti a ba fogbon inu se, ko ni mu inira lowo rara. Nitori yoruba bo, won ni ogbon inu l’ejo nlo.
Ti ija kan ba fe sele, ti enikan ti fi suuru gbe oro kale, tabi fi suuru beere oro lowo enikeji, ko le fa ija rara.
Lilo re; ti eyan ba wa ninu eewu nla ti o sin fe iranlowo awon eniyan, ti iru eni be ko wa fe fi ara bale, a le pa iru owe yii fun wipe, aifelekeeboosi, ni a i reni baani jo ooo.

Tooo, ni hain ni a o ti danu duro fun t’oni, e je ka tun pade lose tombo pelu ase Eledumare.
Gegebi a se mon wipe ile eko ati imo ni aafin ilumoye, aaye wa fun afikun, ayokuro tabi atunse lori eeto ti toni. Eyin eyan wa lori eeto, e funwa ni awon owe ti o se reegi pelu awon oowe ti a na si afefe yii, ki atokun fi mon wipe oowe naa yewa yeeke. E seun

Ogulutu Oro Toni

$
0
0

Hummmmmm mase beru ‪#‎eniyan‬ ju ‪#‎Eledumare lo…
‪woo orewa‬ Kosi nkan tenikan o fi enikan Se,gbiyanjuy latile koju
ota re loni,jeki o mo wipe Akinkanju eyan nio
‪#‎nje‬
O mo wipe toba ti nberu eyan ju yio pada sorare di
Olodumare niwaju re..
‪#‎gbomi_Dada‬
Kosiku tio pa agba taniba polo orire nbe….. Kunfun
Adua kosi magbokan leniyan yio dara fun e……

Ire oooo

Ase.

 
Hummmmmm awa maridi nise Olodumare
‪#‎nje_emo‬ wipe
Tori eniyan buruku ni ose da eni rere
Tori omugo lose da ologbon eniyan
Tori okunrin lose da obinrin
Ose gbogbo re leto leto ni
Tori oloribu lose da olorire……
Ori wa oni buru ooo …..

Ire ooo

Idile Alayo Toni

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin e ku ise o, ko ni reyin lase Edumare. Mo si ki gbogbo awa ololufe eto yi pupo wipe, ibanuje ko ni wo ile alayo enikookan wa o.  Ase.
Olootu e jowo oro kan ni nsele ninu ile mi, ti mo fe ki awon oloye eniyan ba mi da si. Lati igba ti mo ti wa ni kekere ni mo ti korira ki oko ati iyawo maa ja, koda maami a ma so fun mi wipe ti awon ati baami ba ni gbolohun aso ninu ile lasan nse ni ara mi ma n gbon ti otutu yoo si bere si maa mu mi. Ni akoko ti mo wa dagba tan ni mo wa korira iwa yi julo, koda ti mo ba ri oko ti n na iyawo re, nse ni n o maa wo iru okunrin be bii were ti opolo re ti daru, ti ko si mo ohun ti o nse.
Ni bayi emi pelu ti di oniyawo nile, Isele ti o wa nsele simi bayi wa fe mu mi si iwa hu, EMETA otooto ni iyawo mi ti fun mi ni igbati, afi bi eni wipe arabinrin yi ti se ise ologun ri ni, awon igbati wonyi kii se igbati ti o rorun rara, igbati ti ma n fa otutu fun eniyan ni. mo si ti ba Eleda mi se ipinnu wipe nko le gbe owo mi soke na iyawo mi laye. Beeni mo korira ikosile pupo.
Oro yi wa fe toju sumi, tori ni akoko ti isele yi sele, mo pe awon obi arabinrin yi mo si fi ejo omo won sun won, looto won pe iyawo mi ni akoko yi ti won si baa so eyi ti nje okodoro oro sugbon leyin re ni arabinrin yi la mi ni ifoti elekeji, leyin elekeji yi ni mo pe awon ebi mi ati ebi iyawo mi pelu ti gbogbo won si panu po da soro yi ti iyawo mi si n wa omije loju ni ojo yen loun wipe iru re ki yoo waye mo. Afi bi arabinrin yi se la mi ni ifoti eleketa ni ose ti o koja yi.
Mo ti wa rii bayi wipe arabinrin yi ko le dawo iwa yi duro laisi atunse, ni ojo isinmi ti o koja lo yi ni emi ati awon ore mi meta kan jo wa nile oti, beeni oro yi wa n gbe mi lokan, ni mo fi ogbon gbe oro yi kale lati gbo amoran lenu awon ore mi, ni mo tenu bo oro wipe aburo mi kan ni o ma fi ejo iyawo re sun mi o, nse ni o wipe emeta otooto ni iyawo oun ti la oun ni ifoti, beeni oun si ti fi ejo re sun awon obi re lopo igba sugbon ko si ayipada. Oun si ti ba Eleda oun pinnu wipe oun o le gbe owo soke na obinrin laye, beeni oun o fe ko iyawo oun sile leyin omo meji, iyen ni mo ni ki n gba amoran lenu yin. Okan lara awon ore mi ti oruko re nje Kola ni o ko soro, e gbo bi Kola ti wi.

“Ore iyawo aburo re gba aburo re leti ni emeta otooto, ko si ri nkan se sii, se won nse ere ori itage ni abi tooto ni oro na? se sulu ganbari ni oruko aburo re ni? Haaaa awusubilahii, emi laye mi, abi won o san owo omogo lojo ikomo aburo re ni? Iwo gan o si wa mo iru esi ti o le fun-un, woo ore esu ni won fi n wo esu, ma si foko mi se ona ojo kan ni a nko o, toba se akoko ti iyawo re dan an wo ni o ti daa pada fun Un ni, walahi ko ni dan iru re wo mo, obinrin yoo gba emi leti, kamari ni Poolu wi…… ”

Jimo ekeji lara awon ore mi ko je ki Kola dele ti o fi gba oro moo lenu, ni iyen wipe ” Kola kilode ti Iwo ki n fara bale bayi, waduwadu sa ni gbogbo nkan tire, se okun a maa wo ruru ki a waa ruru ni? Sebi won ni ti oko ba je agutan kii iyawo je ewure ni, ti iyawo ba si je agutan oko re pelu yoo je ewure, eko gbigbona nfe suuru jare. Ti o ba si wa da ifoti luu ti iyen si subu lule rogbondan nko se o mo wipe o di apaniyan niyen? Ni Jimo koju si mi ti o si mi kanle ti o bi mi leere oro “Hmmmm ore nje o tie bi aburo re, iru iwa ti o hu ti o fi di ogun onigbati? Ni mo daun wipe, o ni ti awon ba ni ariyanjiyan lasan ninu ile ni o. Ni Jimo tun bi mi wipe se aburo re si maa n se ojuse re ninu ile gege bi oko? Ni mo daun wipe, looto nko ba won gbe sugbon o ngbiyanju. Ni Jimo daun wipe nibi ti oro de yi toba je ododo ni gbogbo idaun re wonyi, so fun aburo re wipe ni ojo ti iyawo re ba tun daa lase, nse ni ki o gbe sinu oko ki o si gbee lo odo awon obi re, ki o yonda omo won fun won laaye, so fun Un wipe ko gbudo naa o….”

Jimo koi ti danu duro ti Kola fi da oro moo lenu, ni o wipe, “abi e o maa gboro se amoran gidi ree, ki o ko iyawo re? Ti o ba wa ko onigbati ta ni o mo boya elese tabi onigigigbo ni yoo tun fe? A ni ki o koo leko ti ko duro ko nile won, Olorun o ni je ki n rina ninu konga, emi laye mi haaaaaa” nigba ti mo rii wipe fanfa oro yi ti fe maa di nkan miran laarin awon mejeeji ni mo da won lekun, ti mo si wa koju si Tunde iketa won wipe, ore se oti ni ko je ki o da soro ile yi ni? Ni Tunde daun wipe:-

“Oro wo ni o fe ki n da si, se oro rurun ti e nso yi abi omiran? Iyawo aburo re gbaa leti ni emeta otooto ko si ri nkan se sii, duro na se e ro wipe gbogbo okunrin ti won n na iyawo won ni kii se okunrin gidi ni, abi e ro wipe gbogbo awon okunrin ti o ko iyawo won sile ni ika eniyan? Sebi eniyan eleran ara ni gbogbo wa, ti obinrin ba fitina eniyan nigba miran, nse ni yoo dabi ki o yo ibon ti won, emi ti o nwo yi, mo korira ki okunrin maa na obinrin ju igbe lo sugbon lojo ti yoo sele, koda iyawo mi ti je igbaju ati igbamu bii mefa ki nto mo wipe iyawo mi ni mo n na, woo emi o ni ki aburo re na iyawo re o, sugbon amoran temi ree, niwon igba ti aburo re ti fi ejo iyawo re sun fun awon ebi mejeeji ti kosi si ayipada, aburo re ko si fe na iyawo re beeni ko fe ko iyawo re sile, ennnn so fun Un wipe, TI IYAWO RE BA GBA A NI ETI OTUN, KI O YI TI OSI SI, BI O SI GBA A NI TI OSI KI O YI TI OTUN SI, KI WON MAA BI SII, KI WON MAA RE SII, KI O SI MAA GBA YINNNN NINU IFOTI, ko ju baun lo”

Bi Tunde ti danu duro ni gbogbo won bu si erin, ti a si dide lori ijoko, bi mo ti dele ni ojo ti a nwi yi ni mo n da oro na ro, mo nro oro awon ore mi lokookan ewo wa ni oluware yoo se bayi, oro Tunde ni o tie je kayefi fun mi, KI N MAA BI SII, KI N MAA RE SII, KI N SI MAA GBA YINNNN NINU IFOTI. iyen ni mo se ni ki n fi oro na to yin leti ki awon ojogbon eniyan la mi loye, iru igbese wo ni a ngbe siru oro bayi, ewo ninu amoran awon ore mi wonyi ni o see tele, bi ko si si eyi ti o dara, e jowo ki ni ki nse bayi? ”
Oro ree o eyin oloye eniyan, paapa julo eyin baami ati maami nile, eyin ojogbon eto idile alayo, e jowo ti eniyan ba wa niru ipo bayi, ki ni sise gan, se were ni a fi nwo were ni abi ki a kuku see ni orisa bi o le gbe mi, se mi bi o ti ba mi? Abi ki oluware kuku maa muu mora ki a gba wipe iya ife ni? Eyin ojogbon oro ree oooo

Idajo mi ree…

$
0
0

Leyin gbogbo atotonu awon agbejoro mejeji ati iwadi
to peye, ariipe ojebi esun ti a fikan e, nitori na idajo
mi ree, ile ejo yi so e sinu:
i) igbega;
ii) aseyori;
iii) idunnu;
iv) ayo;
v) ire owo;
vi) ire omo;
vii) alafia;
viii) ati emi gigun,
lati isinsin yi lo ati titi lailai… Ari bee, ase bee… O seyi yio san wasi ire gbogbo…

Obara Oturupon/Obara Tiele Corpus by Ifa Chief Priest

$
0
0

Good morning my people, how was your night? Hope it was enjoyed. I wish you all happy new month, may this month bring us everlasting joy and happiness amen.

It is OBARA OTURUPON/ OBARA TIELE corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice so that he/she may live long on the earth.
Hear what the corpus said: A wise one use to live long and became an old but a fool person will be moving slowly like ifarifa cast divined for olofin when he was advised to offer sacrifice so that he may live long and become an old like his forefather, two kola nuts, ram and seven shillings and he complied, aftermath olofin live long on the earth in a sound health and in a convenient situation, he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising GOD.
My people, I pray this morning that we shall live long on the earth in a sound health, as the death rate is rampant may God do not count us with those that will die suddenly and this month shall be a month of breakthrough to everyone of us amen.
YORUBA VERSION : Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi o? Aku ori rere osu tuntun to tun soju emin wa o, osu yi yio je osu ayo ati idunnu alailopin fun wa ase.
Odu ifa OBARA OTURUPON/OBARA TIELE lo gate laaro yi, ifa yi gba eniti odu ba jade si niyanju wipe ki o rubo daradara ki o baa le dagba daradara laye o, ki o ma baa fori seku.
Ifa naa ki bayi wipe: ologbon eni ni dagba ti ndarugbo kangerekangere omugo eniyan a maa se sii bi ifarifa a difa fun olofin lojo ti won sope ko karale ebo ni ki o wa se, ki o baa le gbo ki o baa le to ki o baa le fowo pawu ki o baa le ferigi jobi, obi meji, segi agbo ati oke meje owo olofin kabomora o rubo won si se sise ifa fun, seni olofin wa dagba to darugbo kangerekangere ninu alaafia ara o wa njo o nyo o nyin awo awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami laiku kangiri aiku kangiri ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo wa ni ao dagba ti ao si dogbo ninu ola nla, ayo ati alaafia ara, ao fowo pa iwu ao ferigi jobi ao si fagbada din eran, bo se wu ki iku maa paniyan to ako ni bawon nipin nibe, ako ni ku iku ojiji o lagbara Orunmila mimo alagbawi wa aaaseee. ABORU ABOYE OOO.

Chief Priest @Faniyi Temple Consultantant,
Faniyi David Osagbami.


Llegando a oke igeti home de Orunmila.

Gbiyanju lati toju obi i re !

$
0
0

Ojumo to mo wa lonii, ojumo ibukun, ojumo
igbega, ojumo aseyori, ojumo ire, ojumo
itunu, ojumo ayo, ojumo idunnu ni yoo je
fun gbogbo wa lase Edumare(Ase).

‪# AKARA IMORAN‬ : Gbiyanju lati toju obi i re,
niwon igba ti obi i re n be laye; eyin ti E ko
ba ni obi laye mo, E maa se saara fun oku
orun. E ranti wipe ‪#‎Iya‬ ni wura, ‪#‎Baba‬ ni
dingi. Ayo ni ooo.

A ku ojumo oooooooo!

$
0
0

Oba to silekun ojo oni, yoo sina ayo fun wa, yoo sina aje fun wa, A ko no seru egbe wa, ire ayo wa ko ni fo wa ru(Ase).

‪#‎AKARA_IMORAN‬ : Ma se gbo oro okere, gbiyanju lati wadi ohun gbogbo daju, ki o si di eyii to je ododo ibe mu. Nitori oro okere, bi ko lekan, o le dinkan. Ayo ni ooo.

E fu’n Foto yii ni Oruko

$
0
0

E daku’n e be wa fu’n foto yii ni Oruko ka’n to dara!

#‎OkeItase2016‬! Preparation of the World Ikin

$
0
0

Ikin ifa agbaye/world ifa sacred palm but…we dem boys getting it ready for the festival… Yay🙌🙌🙌

See more photos after the page break

Sun re O! Henrietta Kosoko

$
0
0

Hummmmmm Erin wo ajanaku tisun bi Oke eyin ka ile Erin wo porogodo,okoko fo omi okoko danu haaaa sebi eyan Se nku re Oga oooo…….Orun mo kanju Ojo eda oni se ooo

Odo Iwoyi – 3

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo e ku eto o, e jowo nko mo Yoruba ko daradara, eyi ni ko je ki n le se alaye oro mi ni kikun sugbon e jowo e ba mi fi oye gbe niwonba ibi ti mo koo de.

Omo owo ni mo wa ti gbonmi si omi o to fi sele laarin awon obi mi, ti eyi si se okunfa iyapa laarin awon mejeeji. Odo maami ni mo dagba si, ni akoko yi ile oko miran ni maami wa, tosi je wipe oko maami yi ni mo gbonju mo gege bi baba mi tori bi baba gan ni alagba yi n se si mi koda opolopo ti won wa ni ayika ko mo titi di oni wipe arakunrin yi ko ni baba ti o bi mi lomo.

Maami ko setan lati so ododo oro yi fun mi, sugbon ni akoko ti mo ti balaga ni arakunrin yi pemi, ti won si so opo oro tutu fun mi wipe awon o Setan lati ba mi lokan je sugbon awon fe ki n kan mo okodoro oro ni, lojo yi ni alagba yi je ki n mo wipe awon ko ni baba ti o bi mi lomo.

Leyin eyi ni mo bi maami wipe ta ni baba ti o bi mi lomo gan? Maami sun opolopo ekun ni ojo ti a nwi yi, ti won si wa da mi loun wipe awon setan lati se alaye bi n o se ri baami sugbon awon o le ba mi de ibe tori oru ati osan kii pade, wipe awon o le foju kan baami lae.

Ki n ma fa oro gun mo lo ri baami, ti baami si gba mi gege bi omo, won si wa wi fun mi wipe igbakugba ti mo ba nilo iranlowo awon ki n ma kan si awon sugbon awon o fe ri maami o. Nje ki ni o sele gan baami wipe oro na koja agbara mi wipe ki n menu kuro nibe.

Isoro ti mo wa ni bayi ni wipe osu ikeje odun yi ni igbeyawo mi yoo waye ti baba ati iya mi si gbudo wa nibe, mo si ti ba maami soro lopo igba sugbon nse ni maami yari kanle wipe niwon igba ti baami yoo wa ni ijoko lojo na, awon ko le yoju sibe, beeni baami pelu wipe ti maami yoo ba yoju si ibi ayeye na, awon ko ni lee wa nibe nitori sooso meji ko gbudo foju kan ara won.

Oro yi wa toju sumi, koda gbogbo awon agbaagba ti mo mo ni idile mejeeji ni won ti da soro yi sugbon nse ni awon mejeeji faake kori wipe ayafi ti nko ba fe ki alafia o joba nibi ayeye na. Baami wipe awon setan lati ran mi lowo ni gbogbo ona sugbon awon ko le joko po pelu maami lae, won si wipe koda ti mo ba ni elomiran ti o le joko pelu maami o ba awon lara mu.

Oro na ko wa fe yemi mo, iyen ni mo se ni ki n fi to eyin ojogbon leti ki e la mi loye, iru ogbon wo ni a da soro ile yi?. Se maami ni ki n mu pelu mi ni abi baami? E jowo e la mi loye o”

Hmmmm Oro re o, Eledua o kuku ni je ki a rogun ti yoo gbe wa pamo lojo eye omo wa. Abi iru ki leyi? Eyin oloye eniyan, e jowo e ba wa da soro ile yi o..

Lati Owo Abel Simeon Oluwafemi


Idile Alayo Toni 09.06.2016

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. Beeni mo ki gbogbo awa musulumi ododo wipe a ku ongbe o, emi wa ti o bere re ni yoo pari re lase Edumare.

E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Eledua yoo tun ile ati ona tiyin na se o, mo si ki gbogbo awa ololufe eto Idile Alayo wipe ile alayo gbogbo wa ko ni di ibanuje lase Edumare. Ase

Olootu oro kan ni o n dun mi lokan ti mo nilo amoran awon ojogbon, odun iketa ree ti mo ti wa nile oko, ti Eledua si ti fi omo kan da mi lola, ise awon ti nko ile ni oko mi nse ti Eledua si gba fun un lenu ise owun. Ko si ipinle na ni orile ede wa nibi ti oko mi kii tii lo se ise, nse ni won ma n pee lotun losi tofi je wipe oko mi le lo ni osu kan si meji nigba miran laiwa si ile.

Looto kii se wipe bi ise se maa n gbe arakunrin yi kiri yi ko dun mo mi ninu nitori mo mo wipe atije atimu ni o nba ka beeni mo si ti mo arakunrin yi pelu ise re ki n to fe e, sugbon ohun kan ti o n sele ti o si n kan mi lominu ni wipe o fere je akoko ti oko mi ko ba si nile pelu mi ni inu mi ma n dun wipe mo ni oko, o fere je akoko yi nikan ni mo ma n ri ayo ile oko, o fere je akoko yi nikan ni mo le fi oko mi yanga sugbon ni kete ti oko mi ba pada de nse ni ebi wa ma n di ebi alariwo.

Oro yi si wa n je edun okan fun mi, tori ti oko mi ba wa ni irin ajo nse ni yoo maa ba mi soro lori ero ibanisoro bi eni wipe laisi emi ko si oun pelu, nse ni awa mejeeji yoo ma da oweke lori ago, opolopo oro apani lerin, opolopo amoran, ati oro tutu lolokan ojokan ni oko mi yoo maa so simi toje ti mo ba soro pelu oko mi tan inu mi a si maa dun, maa si ma dupe lowo ori mi ti o gbe mi pade arakunrin yi sugbon ni kete ti oko mi ba pada sile ni oro yoo wa yi pada. Emi ati oko mi yoo wa maa sebi ologbo ati ekute ninu ile.

Oro yi a si maa gba omije loju mi lopo igba tori nse ni mo n ro wipe se nkan miran wa nidi oro yi ni? Koda mo ti gbawe gbadura lori oro yi sugbon ko si ayipada, opolopo igba ni mo ti ji oko mi ni oganjo oru ti mo si bii leere wipe ki ni ma nfa sababi ede aiyede wa gan ti yoo si daun wipe emi ni mo ma n faa, nje ona wo ni mo fi ma nfa gan? Ni yoo ba wipe ki n lo ye ara mi wo.

Oro yi le ma ni itunmo si elomiran sugbon ohun ti n gba omije loju mi gan ni, abi ewo ni ki eniyan ri oko re ti o ye ki o je idunnu re ti yoo si wa je ibanuje fun oluware, ti a ba si n soro lori ago nse ni yoo dabi eni wipe awa ni loko laya ti o dara Julo ni agbaye. Beeni awon oro ti ko to nkan ni o si ma n saba da gbonmi si omi o to yi si. Oro yi ti wa toju sumi pata pata bayi, iyen ni mo se ni ki n fi lo eyin iya ati baba mi ti e mo nipa oro loko laya tori won ni iriri sagba ogbon.

E jowo ki ni ma n se okunfa iru isele yi gan ati pelu ki ni ona abayo, e dakun eyin oloye eniyan, e la mi loye o”

Hmmm oro ree o eyin ojogbon ati oloye eto idile alayo, aja ti o ri olowo re lokere, ti o si kun fayo, ti o nfo soke sile ti olowo re wa sun moo tan ti ngbo fita fita, se aja ni ki a da lebi ni abi olowo re ni ki o ye ara re wo? Eyin ojogbon o dowo yin o

`Abel Simeon Oluwafemi

Ire otun, ire osi, ire niwa..Iree o

$
0
0

Iree! Apa mejeeji l’eyele fi n ko’ree wo’le. Ire otun, ire osi, ire niwa, ire l’eyin, ire Olokun, ire Olosa, ko mi a da giriri wole to wa wa!
Aase!

Iwure Owuro 12.06.2016

$
0
0

E MAA WI TELE MI :

*Ori mi wa gbe mi leke abinu eni.
*Ori mi ko ni gbabode ibi.
*Oloore mi ko ni ri mi sa
*Oluwa so egan mi dogo.

*Edumare wa fi ibukun sinu ise mi

*Lojo tebi n pa ile, emi ko ni si nile

*Lojo tebi n pa ona, emi ko ni rin lona(ASE)

 

Arewa Asa Toni

$
0
0

Ayeye Ojo Ibi Iyawa Toyin Adewale

Ojo ibi se koko Ojo ibi se pataki eo ni mo Ojo ibi yin
saburu,Ododun ni sapo nruwe Ododun ni mariwo yo
Ododun la nri omo obi lori ate, emi yin o se opo
odun laiye ooo…. Igba Odun Odun kan nio…. Ire
oooo

toyin

ko ko ko. Tani yen o?

$
0
0

Awa ni O! Eyin Wo? Awa Anu,Ire,Iyanu,Owo,OmO, Ayo,Ibukun,Alafia,Igbega,Aseyori,Aabo,Idunu,Itesiwaju, Ojurere Olorun at Emi gigun. Kini e wa o?. Awa lati wa ba iwo ati ebire/ore eyi ti o fe fun ire gbe lati odun yilo atii titi laiye… Ifa kan so ninu odu mimo iji elemere wipe.. Opa run ile baba mi bale oro wanran wanran adifa fun won lode IDO ibi ire gbogbo won gbe ti sii lo ( ire awon lede pada ni won da ifa si, won ni kiwon karanle ebo ni kiwonse. Won gbo ruru ebo, won gbo eru won tuu )… Nje ire owo,aya,omo,alafia,emigigun, aiku bale oro, eyi ti otisi lo lode ido nko, owenren wen ide lope ki won de…. Pelu ase odumare, ire koni silo lodede eni kankan wa.. Gbogbo eyi ti atun nfe a wole de.. Ase.. Ase… Ase

Viewing all 2260 articles
Browse latest View live