Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all 2260 articles
Browse latest View live

Oruko kan fun arakunrin yii

$
0
0

E dakun, e bawa fun arakunrin yii ni oruko kan ?


Eeto Owe L’esin Oro

$
0
0

A ku deede asiko yii o gbogbo olugbe aafin ilumoye, eeto yin eeto wa owe l’esin oro ni o tun wole de weere yi ooo, e wa nkan fidile ki a dijo gbadun eeto ti toni. Siwaju ki eeto o to bere, mo dupe lowo Eledumare oba aseda ti o je ki a dagbere fun eeto ni ose ti o lo, ti a si tun ni anfaani lati tun pade ni ose yii, Oluwaseun, Olodumare maa je ki enu ope wa o kan ooo.
Mo ki kabiyesi olumoye akoko, moki yeye oba, awon olori laafin, awon ijoye oba, gbogbo igbimon aafin ati awon omo’ba l’okunrin ati l’obinrin.

Eeto Owe L’esin Oro 1
Nje a tun ti de bi a se maa n de gegebi ise wa ni gbogbo ojo mejo, lori eeto yii ni a o ti maa yannnana awon owe ile wa lolokanojokan ti a o si maa ko arawa ni itumo ati lilo awon owe bee. Ni bayii, e je ki a bosi agbami eeto naa.
Owe akoko ti a o maa gbeyewo loni loo bayii: O D’ORI AKAYIN, AKARA DE’EGUN tabi
AKARA D’ORI AKAYIN, O DE’EGUN.
Akayin ni eni ti eyin enu re ti woo tan, ti ko le je ohun to ba lee tabi gbóorín. Koda akara bo se fele to, tun le lee die lenu arugbo ti ko ni eyin, tabi ti akara ba gbee wonu daradara, arugbo ko ni le je e lajegbadun, niru asiko yi, ofooro ni won maa n fe e je.
LILO; ti nkan ba n lo deede, ti awon asiwaju se nkan naa ti kosi isoro, ti aresa see ti ko huun, ti orangun aga see ti ko kabamo, to wa dori enikan ti ko wa ri bee, yala boya nipa aisi agbara to fun eni be, tabi boya won fi ofin kan dee. Eyi ni wipe igba ti nkan d’ori enikan (akayin), eni ti ko lagbara, ti o lowo, ti o lola, ti o nipo, ti ko je nkankan lawujo) ni nkan yipada.
Baba kan le bi omo mefa, ko ti ran awon marun nile oko, kiru baba yii wa ku tabi ki ise bo lowo re, lai tii ran enikefa, owe yii le waye pe “akara d’ori akayin o de’egun”.
Owe keji ti a o maa gbe yewo loni loo bayii: WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI, KO SA TI FUNFUN tabi
WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI KO SA TI LE JE MOSA tabi
WONTI WONTI KO L’EYIN, BI EYIN BA JE MEJI, KO SA TI LE JE OBI, tabi ERAN.
Eyi ni wipe kii se dandan ki eyin po ipo yaa lenu, sugbon ki o se ohun ti a fe ko see.
Kii se pe ki nkan po repete, kii se pe ki omo po jaburata…..sugbon die naa ti eyan ba bii, K’Oluwa je won o jeeyan, ki won yan, ki won yanju.
Ti eyan ba bi omo meji, ti okan je dokita, ti ekeji je noosi, tabi looya, kii i se iyalaya eni to bi mewaa, tokankan o ni laari. Idi niyi ti yoruba fi se akiyesi pe kii se opo nkan lo pin dandan bikose iwulo, anfaani ati laarija re.
A tun le lo owe yii, fun apeere ti a ba wa ninu egbe kan ti opolopo awon to wa ninu egbe naa ko mu egbe naa ni okunkundun, a le pa owe yii lati fi yewon wipe, ko ba je awa meji pere ni a n se ojuse, iyoku kekere ni, hanti hanti ko l’eyin, bi eyin ko ba ju gaaga meji lo, ko sa ti le gba eran mu.
Toooo, ni hain ni a o ti danu duro fun ti toni, gegebi a se mon wipe agbala imo ati ooye ni aafin olumoye, aaye wa fun afikun, atunse tabi ayokuro ki o le ba je eko fun gbogbo wa, eyin eyan wa, eyin naa e gbiyanju ki e funwa ni awon owe ti itumo ati lilo re fi ara jo iru owe ti a naa si afefe yii o ki a le ba tun ri ogbon ati imo kan diimu nibe. E seun

Yoruba Arts Festival 2016

$
0
0

The Yoruba Arts Festival in London returns for its 7th year through thick and thin and invite everyone who can make it to come and have a kick about, some African food, African market, music and laughter. Free entry. 12-9pm…

Photos: Check out Yoruba Combs & Hair

$
0
0

Yoruba believe that the head “ori” holds ones destiny.

“Ori is not a divinity. The Ori is what holds an individual destiny. The Ori is in control of one’s daily ups and downs. Ori could be considered as personal god or guardian angel who will accompany each of us for life. Even the gods have their Ori which directs their personal lives. Ori is human consciousness.”Iyalorisa Omitonade Ifawemimo

 

Continue to see more photos of Yoruba Combs & Hair

Iyawo elese-osun ati oko-iyawo-elese-osun

$
0
0

Base fe kori benan lori emi lao ni yo si, leyin iwa ewa lotun ku pelu ase Edumare iyawo elese-osun ati oko-iyawo-elese-osun ori koni tako yin leyin igeyawo yi ati titilailai, ogede ki gbodo koya agan, iyawo yo finu soyun yo fi eyin gbe omo-pon, eyin iyawo koni mo eni ooo, niwo yi amodun ibeji-lantilanti pelu ase-edua

Oro re e gbe ye wo

$
0
0

hmnmmmmmm ojulu oooo!, E gbo nti omodekunrin olorin yi(adeekunle gold) nfi orin nwi? O nipe okunrin olowo-agbaye(aliko-dangote) yi ko ni ori-meji o ni oun nan fe lowo bi dangote oun fe gun moto-boginni(range-rover) oun fi kadara we karaole oun fi ayanmo we anamo o ti gbagbe pe eledua loni ded, o ti gbagbe akunleyan ati adayeba, o ti gbagbe pe kadara ko se danu. Ni otito a pe mora lape temidire sugbon kadara kose d’ogbon si e bami sofun omokunrin yi pe kadara kose fise idije. Oju-itere ojulowo omoyorubaatatahmnmmmmmm ojulu oooo! oro re e gbe ye wo, e gbo nti omodekunrin olorin yi(adeekunle gold) nfi orin nwi? o nipe okunrin olowo-agbaye(aliko-dangote) yi ko ni ori-meji o ni oun nan fe lowo bi dangote oun fe gun moto-boginni(range-rover) oun fi kadara we karaole oun fi ayanmo we anamo o ti gbagbe pe eledua loni ded, o ti gbagbe akunleyan ati adayeba, o ti gbagbe pe kadara ko se danu. Ni otito a pe mora lape temidire sugbon kadara kose d’ogbon si e bami sofun omokunrin yi pe kadara kose fise idije. Oju-itere ojulowo omoyorubaatata

See where to buy Items like Opon Ifa, Books, African Fabric, Orisa beads and others

$
0
0

Look no farther for your African Spiritual Items like Opon Ifa, Books, African Fabric, Art works, Orisa beads, Traditional Songs, Brass items, Kolanut, Spiritual Item…Ancestral Vision presents…..all at affordable prices…IRE O!!!

Ifa staff(Iroke Ifa) and Ifa divination tray(Opon Ifa) at affordable prices…. ORDER NOWWW AT ANCESTRAL VISION ARTS AND CRAFT

Ìyá Alágbàdo (Roadside Corn Roaster)

$
0
0

Painting by Prof. Moyo Okediji
acrylic on paper.
48″ x 48″
2016


Iwure Owuro Toni – 24.05.2016

$
0
0

E MAA WI TELE MI :
……….
*Eledumare tete wa pa mi lerin ayo.
*Ajalu buruku ko ni sele si mi.
*Edumare ba mi segun alatako.
*Emi ko ni subu fun ota yo.
*Apari inu mi ko ni ba tode je(Ase)
…………………………………………….
E yin redio(radio) yin si ikanni UNIQ
103.1FM, Ilesa, ni dede agogo mewaa abo
owuro (10:30am) oni; fun akotun eto ISESE
OMO OODUA.

Ogulutu Oro Toni – 24.05.2016

$
0
0

Wo binu ba nbio masoro, tinu re basi ndun mase ile ri, fi eniyan buburu sile saye re.
# wo Mase mura lati gbija arare fija le f’OLOHUN,ohun nikan loba elesan…..

Ire oo

 

Eeto Owe L’esin Oro – 3

$
0
0

A ku deede asiko yii o ni aafin ilumoye, moki gbogbo wa kaabo si akotun eeto yin, eeto wa OWE L’ESIN ORO, oro l’esin owe ti oro ba sonu owe ni a o fi waa jade.
Ope nla lo si odo Oba Eledumare ti o je ki a tun ni anfaani lati tun pade leyin igba ti a dagbere ni ose to koja, enu ope wa koni kan oo. Moki kabiyesi olumoye akoko, awon olori, gbogbo ijoye patapata, awon igbimo aafin, omo’oba l’okunrin ati l’obinrin ati gbogbo olugbe aafin patapata ni moki n o ni olodi kankan oo.
Awon baba wa a ni ‘adebi eeyin maa sii, agbalagba ole nii’, ni bayii, e je ki a kanlu agbami eeto.
Lori eeto yi ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan bi Olorun ba se gbawa ni aaye mon, ti a o si maa se alaaye itumo ati lilo awon owe naa.

Owe akoko ti a o gbeyewo lo bayii: OJO OWURO TI N BI OLOWO NINU, OLOWO GELETE, IWOFA NAA GELETE.
ITUMO; Fun apeere, olowo le je agbe to ni owo lowo, paapajulo ni aye atijo, ti o ni owo debi gee, ti awon eyan maa n wa ya owo lowo re, ti eyan ba si ya owo beyen ni aye atijo, o nilo oniduro, oniduro yii ni eni ti oju owo n pon yii yio fi duro, eyi to tumo si wipe yio maa ba olowo yii roko, yena ati lati maa se awon gbogbo ise agbara. Eyi ko ni din owo yii ku ti eni to yaa owo ba fe san pada o, oniduro yii ni won n pe ni IWOFA, o di ijo ti awon ebi re ba to ri owo san ki iwofa to le gba ominira lodo olowo re, ti eni to ya owo ko ba si ri owo san, iwofa di ajemogun niyen oo. Olorun koni fi oju owo pon wa ooo.
Tooo! Ise ti iwofa wa se ni ise oko, ti ojo ba wa suu tabi ti ojo ba nro arooda, bawo lo se maa ri, iwofa ko ni le lo roko, inu olowo o si nii dun…..agaga ti o ba lo je ojo owuro kutukutu, olowo a wa waa gelete lori ibusun, iwofa naa a waa gelete tabi ko jokoo, ko ni le sise.
ITUMO IJINLE; ti ohun kan ba sele to n di awon to n sise ooya won lowo, inu awon oga won o le dun, asiko yii l’owe yii maa n waye.

Owe keji fun toni lo bayii: ENI A GBOJU OKUN LE, KO JO ENI AAGBA.
Okun aagba je okun to le daada to see di igi tabi eru lati oko wa si ile. Ti a ba wa ro pe enikan lo le ran wa lowo, tabi pe enikan lo le se ohun kan, ti a ti gba eri iru eni bee je, to waa ja wa kule, iru asiko yii ni owe yii maa n foju ba ita wipe, “eni a gboju okun le, ko jo eni aagba”. Ti a ba ti n foju kan wo enikan tabi ti a ti gbe gege si ipele kan ti eni yii waa ja wa ni tanmo-on, asiko yii la maa n pa owe yii, eyi ni wipe ipele tabi ibi ti a fi eni yii si, a o ba a nibe.

Owe keta fun toni lo bayii: TI AGBALAGBA BA N BA OMODE JE IYAN EEWU L’OKO, GANMU GANMU IMU ENI NI N WOO.
iyan eewu ni iyan ojo keji, iyan yii maa ti wu, won maa wa re eewu ori re yii kuro ki o le ba see je, ko fii be toba fun agbalagba lati je iru iyan bayii, awon omode ni won maa n gbe fun. Ti agbalagba ba wa jokoo pelu omode ti won wa jo n je iru iyan yii, irun imu ati enu agbalagba yii ni omode naa yio maa wo, nitori o ti di dandan ki irun yii duro sarasara. oun gan koni fii be kobi ara si ounje naa nitori ounje naa ko yanju daada.
A maa n lo owe yii ti eyan ba n ba omode se apaara tabi eefe, ti omode naa wa ti fe so di arifin mowa lowo, ti ko fe bowo agba funwa mon. A le pa owe yii wipe, ti agbalagba ba n ba omode je iyan eewu l’oko, ganmuganmu imu eni ni nwoo.

Tooo, ni hainn ni a o ti se ewe le fun ti toni, agbala imo ati ogbon ni aafin ilumoye nibii ti a ti n ko arawa l’eko ti a si n ya ara wa l’ogbon. Aaye wa fun afikun, ayokuro tabi imoran lori eeto OWE L’ESIN ORO yii. Eyin eyan wa, e dasi eeto naa nipa wipe ki e funwa ni awon owe ti o tun ni ibamu pelu awon owe ti a na si afefe yii, ki atokun fi mon wipe, e gbo agboye awon owe naa, a o maa reti yin ooo. E seun

Odo Iwoyi – 2

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa. Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

 

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Eledua yoo San yin lesan ire o. Beeni mo ki gbogbo awa ti a ndasi eto yi wipe, a ku atunse, Eledua yoo tun ile ati ona enikookan wa se o. Ase

Olootu e jowo oro kan ni nbami lokan je, ti ko si fe yemi mo, eyi ti mo nilo amoran awon ojogbon eniyan lori re. Eni odun mokandinlogbon ni mi bayi. Isoro kansoso ti mo ni laye ni wipe lati igba ti mo ti balaga nko ri odokunrin kan ti o konu ife si mi ri. Oro na wa je kayefi fun mi, Koda mo ti gbadura gbaawe lori oro yi, sugbon nko ri ayipada, beeni mo rewa lobinrin ti nko si ni alebu kokan lara, eyi gan ni oro yi fi je iyalenu fun mi. Looto kii se wipe okunrin kii denu ife ko mi o, sugbon isoro ibe ni wipe, awon okunrin ti won ti laya nile koda awon miran ti ni meji beeni won yoo si maa da mi laamu wipe, awon yoo fe mi dandan ni.

 

Ohun ti o jomi loju julo ni wipe lati ile eko girama ni isoro yi ti bere, ipele ikarun ni mo wa ni odun yen loun ti oluko mi kan ti o ti laya meji nile bere si ndami laamu. Ohun ti o semi ni kayefi ni akoko yen loun ni wipe pelu gbogbo bi mo se n yakayaka okunrin yi ko deyin leyin mi, oro yi le debi wipe mo so fun awon obi mi wipe ti won ko ba paro ile eko mi, nko ni Ka iwe mo, sugbon o se mi ni kayefi wipe nkan kanna ni mo dojuko ni ile eko miran ti mo pada si, beeni o si tesiwaju ti mo fi wo ifasiti, koda o to akoko kan ti mo ma n fi ogbon ti ara mi si awon odokunrin lorun sugbon opo won ni ko wo ibi ti mo wa, awon ti yoo ba si wo ibi ti mo wa yoo kan se mi bi o ti wu won laarin osu melo kan ti won yoo si pami ti ni. Niwon igba ti o kuku je wipe emi ni mo gbe ara mi lo ba won.

 

Isoro yi tesiwaju titi mo fi pari eko ifasiti ti mo si bere ise, ni bayi arakunrin kan ni mo pade ni odun ti o koja, oga ile ise kan ni alagba yi, ore ni arakunrin yi ati oga ile ise ti mo ti n sise, alagba yi denu ife ko mi, ti o si se ileri lati fimi se aya, gege bi ojo ori alagba yi, mo bi won ni akoko na wipe, pelu ojo Ori yin yi ti e si je omo Yoruba se rara ni e koi tii ni iyawo ni? Alagba yi si da mi lohun wipe looto awon ti ni iyawo ri ti awon si ti bi omo meji sugbon ni bayi awon ko si pelu obinrin kokan. Opolopo ibeere miran ni mo bi Alagba yi, ti won si da mi lohun leseese. Mo tesiwaju pelu Ogbeni yi, leyin bi osu mejo ti a ti nba ara wa bo koda mo ti mu arakunrin yi lo Odo awon obi mi, ti a si ti n gbero lati se idano. Sugbon ni osan ojo abameta kan ti mo lo ki arakunrin yi ni ile, nse ni ero ibanisoro mi yonu ni ojo na, ti mo si nilo lati pe egbon mi ti won je akobi wa, se ori simu kadi mi ni onka ero ibanisoro won kuku wa. Ni mo be arakunrin yi ki o ya mi ni ero ibanisoro re, ki n fi siimu mi sii lati fi ri onka ero ibanisoro egbon mi.

 

Bi mo ti fi siimu mi si inu ero ibanisoro alagba yi, ni ore won kan wole de, ti mo si wonu iyara lo, ki n maa ba di won lowo, koda nko mo ohun ti mo te ninu ero ibanisoro yi, sa dede ni mo ri opo itakunroso alagba yi ati obinrin kan, ti won si n soro bii loko-laya. Opolopo itakunroso wonyi ni mo ri ni ori wasabu arakunrin yi ati opo miran ni abala atejise. Awon oro wonyi wa n se mi ni kayefi. Logan ti ore arakunrin yi lo tan, ni mo pee ti mo si fi awon itakunroso wonyi han an, ti mo si bii wipe ta ni eni yi gan? Alagba yi si wa tenu bo oro wipe

“Ni ikorita ti a de yi, mo Setan lati so ododo oro fun e, woo mo fi Eleda awon obi re mejeeji be o darijimi, ife ti mo ni si o ni ko je ki n le so okodoro oro fun o lati eyin wa, tori mo se akiesi wipe ti o ba mo wipe mo laya nile, o ni gba fun mi, idi niyi ti mo fi daa bi ogbon. Iyawo meji ni mo ti fe ri sugbon okan ti se alaisi ti ekeji si wa pelu mi di oni. Jowo mo fi Olorun be o, darijimi, mo ni ife re tokantokan ni, mo si setan lati fi o se aya”

Bi alagba yi ti n so oro ni omi n da loju mi, looto kii se oro yi ni o ngbomije loju mi bikose oro igbesi aye mi nitori eyi kii se akoko ti iru Isele yi yoo se simi. Bi arakunrin yi ti danu duro, ni mo daa lohun wipe mo ti gbo, ti mo si kuro niwaju re. Ti mo kori si ona ile mi, mo wa nro oro na lati ojo na koda o toju sumi, abi ta ni yoo gbadura ile olorogun fun ara re, obinrin wo ni inu re yoo dun lati gbo wipe obinrin miran n fe oko oun?

Awon ibeere wonyi ni mo n bi ara mi, ni mo fi oro yi lo egbon maami kan tori maami ko si laye mo. Ni won si wipe pelu gbogbo alaye mi wonyi, o seese ki o je ayanmo temi niyen. O seese ki o je okunrin ti o laya nile ni a ko mo mi lati fi se ade ori. Mo wa n da oro yi ro wipe se o seese ki Olorun ko iru nkan bayi mo eniyan? Nigba ti nko ri idaun si ibeere yi, ni mo fi oro na lo egbon mi kan ti won je alagba ijo. Egbon mi yi si wa nje ki o ye mi wipe, Olorun kii ko ikokuko mo eniyan, won tesiwaju wipe nigba ti Aseda seda awa eniyan, tako-tabo ni o seda wa, beeni gbogbo ohun abemi pata. Olukuluku okunrin ti Eledua seda ni o seda aya re pelu, bakan na si ni gbogbo obinrin pelu. Nitorina ki n ma daba ati fe oko oloko o, ki n duro de akoko Eledumare fun oko temi gan tori oko kan aya kan ni bibeli wi. Nitorina ki n tesiwaju ninu adura, wipe awon pelu yoo maa ran mi lowo ninu adura.

Awon oro wonyi wa n gba omije loju mi abi odun melo ni oluware yoo fi duro bayi? Iyen ni mo se ni ki n gba amoran lenu eyin oloye eniyan. Se ki tesiwaju ninu adura gege bi alagba se wi ni, abi ki n gba kadara, ki n si maa tesiwaju pelu arakunrin yi? E jowo e la mi loye o

Hmmm oro ree o, eyin ojogbon eniyan, e jowo e ba wa fi oju sunukun wo oro ile yi. Se ki arabinrin yi kese bo bata ile olorogun ni abi ki o tesiwaju ninu adura?

`Abel Simeon Oluwafemi

These photos Look Real, But They Are All fine arts

$
0
0

Another exquisite hyper exemplary painting from OLU,

Nigeria best hyperclassic painter…

This person is an immaculate talent, every one of his works of art and fine arts dependably looks so real. Can’t believe
this pictures were painted..

Proud naija..

See more photos  after the page break bellow..

Ounje UNJE Eme Fun T’ooro Yii – 26.05.2016

$
0
0

HUN !
B’o ti wu ki a pe laye to …
A pee lorun ju bee lo…
::::
WOO ORE WA !
‪#‎Igba‬ o lo bi ‪#‎Orere‬..
Bee, ‪#‎Laye‬ taa wa yii ko lo bi ‪#‎Opa_ibon‬
:::::::
DAKUN ORE WA !
So igba-meta yii ninu Ayee re ::
Igba ‪#‎Bibi‬
Igba ‪#‎Dida‬
Igba ‪#‎Dide‬
…….
‪#‎IGBA_BIBI‬ : ni aye ti eda nlo lati igba to ti
bawon ke mowa-mowa sile aye;; igba yii
nikan nigba aimo

‪#‎IGBA_DIDA‬ : ni aye ti eda nlo leyin igba
aimo mo re; Ti eda n rokan ‪#‎kin_laa_da‬ ??
Laye leyin jije,mimu,nina,lilo…
……
‪#‎IGBA_DIDE‬ : ni aye eda ni igba-ikeyin aye re,
Ti o yeki Eda maa beere lowo araa re wipe
‪#‎Nibo_ni_maa_de_si‬ ?? Leyin isemin aye mi…
::::
AKIYESI KAN REE O :: Kii se gbogbo Eda ni
igba meteeta yii maa nba laye idi niyi ti o
gbodo ronu piwada lonii bi o se nfi oye gbe
‪#‎OUNJE_EMI_TOORO_YII‬ je .
::::::::
A KU OJUMO
‪#‎Oni‬ a sanwa s’owo, S’omo, S’alaafia ati
Aiku-baale-oro lase eledua

Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e nse lori eto yi, Eledua yoo pin yin lere o, beeni mo ki gbogbo awa ti a nda si eto yi wipe Olodumare yoo da soro aye enikookan wa o. Amin

E jowo olootu oro kan ni ko fe ye mi ti mo nilo amoran awon ojogbon le lori. Odun keji ree ti mo se igbeyawo, ti Eledua si ti fi omo kan da idile mi lola, isoro kansoso ti mo ndoju ko nile oko mi ni wipe, oko mi ti feran odi yiyan ju, afi bi ounje ni odi yiyan je fun oko mi, ohun ti o ro oko mi lorun julo ni ki oun ati eniyan ni gbolohun aso ki won si maa soro si ara won mo titi lae.

Ohun ti o wa nje edun okan mi lori oro ile yi gan ni wipe, gbogbo eni ti oko mi ba ti ba ja bayi, ni yoo fe ki emi pelu maa yan lodi, beeni emi si korira odi yiyan pupo, koda mo se akiesi wipe, Eleda mi ko feran odi yiyan rara, tori gbogbo igba ti mo ba ti n yan odi ni nkan kii lo dede fun mi mo, koda kii je ki n ri orun sun bi o ti ye. Beeni oko mi yoo si maa pon dandan re fun mi wipe, gbogbo eni ti o ba ti je ota oun, ni o gbudo je ota mi, beeni awon ore oun pelu si gbudo je ore mi.

Ko si rorun fun mi rara lati tele ofin yi. Gbogbo awon ayalegbe egbe wa ti a jo wa ninu ile kan na, ni oko mi kii ba soro, koda opo ara adugbo gan, beeni oko mi yoo si maa ki mi nilo wipe oun ko fe ri ajosepo kan laarin emi ati awon eniyan wonyi. Ni Akoko ti nkoi ti mo arakunrin yi daradara, ti mo ro wipe oro awada ni oro yi, emi a maa ba oko mi gbonu wipe, emi o le maa ba awon eniyan yondi lainidi o, sugbon nigba ti mo se akiesi wipe oko mi mu oro na ni okunkundun ni mo fi oro na to maami leti, maami si wa gba mi lamoran wipe ogbon ni n o da si oro na tori toko lase o, wipe ti oko mi ba ti soro nko gbudo maa gbo lenu, nse ni ki n daa lohun wipe mo ti gbo, ki n si mo bi n o ti maa fi ogbon ba awon ara ile mi lo ti ko fi ni da wahala si laarin emi ati oko mi.

Bayi ni mo bere sii daa bi ogbon, ti oko mi ba wa nitosi nse ni n o jina si awon eniyan wonyi koda oku Kiki kii pawa po. Ti oko mi ba si ti kuro nile, a o maa se ore ara wa, looto inu mi o dun si iru igbe aye yi, sugbon ki n maa ba da ile ara mi ru, mo nfi ogbon see.

Oro kan ni o wa sele ni ose keji seyin, arabinrin kan lara awon ayalegbe wa ni o ya kini ti a fi nlota lowo mi lati sure loo. Oko mi ko si nile ni akoko yi, ko pe si akoko yi ni oko mi wole, bi o ti wole de ounje ni o beere, beeni mo gbe ounje ka iwaju oko mi ti awa mejeeji si n jeun, bi a ti n jeun lowo, ni oko mi gbo ti enikan wa nidi ilekun, se oko mi ni o si sunmo enu ona? Beeni o si ilekun ti o si ba omo arabinrin ti o ya ohun elo ilota lowo mi, ti iyen si wipe mama oun ni ki oun muu fun momi.

Bayi ni oko mi bere sii wo omo yi, ti o si nwo emi na pelu tikategbin, ni mo nro ninu okan mi wipe, mo rogo loni, beeni mo sun mo omo yi ti mo si gba kini yi lowo re, ki oko mi to fo gbolohun kan, nko mo igba ti mo wipe “MI O YA WON O, MO GBAGBE RE SI ILE IDANO NI O” beeni oko mi tenu bo oro ti o si wipe:-

“Sebi mo kilo fun o, o fe gbo abi? Won ti so fun mi wipe alabodi ni e tele, o fe gba abodi fun mi abi? O fe pa mi ki o le jogun mi? Je ki nso fun o, ki o to pami wa jade kuro ninu ile mi, wooo mo njade lo bayi ki n to pada de, nko gbudo ba eyi ti o fuye ati eyi ti o wuwo ninu eru re ninu ile yi, bi bee ko, oku meji yoo ba Olorun nile”

Bi oko mi ti jade bayi ni mo pe egbon oko mi kan lori ago ti mo si kejo ro fun won, beeni awon pelu wipe bawo ni emi pelu yoo ti se bee niwon igba ti mo mo iru eniyan ti oko mi nse? Beeni egbon oko mi yi gbiyanju lati pee ki won baa soro sugbon o ti pa ero ibanisoro re. Bi oko mi ti pada de ti o ri mi bayi afi bi ekun ti o ri aja ni, ti ki baa se wipe mo sa jina loja ti a nperi yi ni Olorun nikan ni o mo ipo ti n o ba wa bayi, bayi ni oko mi bere sii ko ero mi sita ti kosi si enikan ti o lee daa lekun.

Bi ere bi awada bi mo ti dero ile wa ree o, bi mo ti pada de ile wa ni mo kejo ro fun maami, ti emi ati maami si bere si to ojule awon ebi oko mi kiri ki won le baa soro. Beeni won n pe oko mi lori ago loju wa sugbon nse ni o nso fun won wipe toba se lori oro mi ni, ki won ma yo oun lenu mo. Sugbon pelu gbogbo oro arakunrin yi maami ko sinmi bayi ni a gbera o di abule won lodo baba ti o bi oko mi gan, baba yi si wa je ki o ye wa wipe lati kekere ni iwa yi ti wa pelu arakunrin yi, sugbon tobe jube lo awon yoo baa soro, beeni won pe arakunrin yi ti won si baa soro, ti o si wa wipe oun ti gbo, mo le maa ko pada bo nile sugbon ota oun gbudo je ota mi ni, bi bee ko ajogbe po wa ko le rogbo.

Mo wa nda oro yi ro lati ano wipe iru igbe aye wo ni oluware yoo maa gbe bayi? Beeni maami pelu nfi ye mi wipe ohun ti oko mi ba ti fe ni mo gbudo baa fe, obe ti baale ile o kii je iyale ile kii se o, ko si si ile mosu nile wa o. Awon oro wonyi wa n je edun okan fun mi tori afi bi eni ngbe igbe aye inira ni oro na je, bawo ni n o se maa ba awon eniyan yondi lainidi? Gbogbo awon nkan wonyi ni mo nro, ati pada si ile arakunrin yi nse ni o dabi eni nlo si ogba ewon, iyen ni mo se ni ki nfi oro yi to eyin ojogbon leti, tori toba seese nko fe pada si odo ogbeni yi mo, beeni maami o je ngbadun, abi ki ni a o ti se eyi si? Iru ogbon wo gan ni a fi nba iru awon eniyan bayi gbe tori ko tie yemi mo bayi, e jowo e la mi loye o”

Hmmmmm oro ree o, eyin oloye eniyan, bawo ni a o ti se eyi si bayi? Eyin ojogbon eto Idile Alayo, se dandan ni wipe gbogbo eni ba je ota oko gbudo je ota aya re ni? Se gbogbo eniyan ti oko ba nbinu si ni iyawo re gbudo maa yan lodi ni? Sugbon looto iru ife wo ni ota eni le ni si omo eni? Hmmm eyin oloye eniyan e ba wa dasi o, se ki arabinrin yi tete tun ero ara re pa bayi ni abi ki o maa tele baba olofin yi???

`Abel Simeon Oluwafemi


Lakurubututu ! “Omo ya jo, omo le yeni”

$
0
0

Omolade,Omolowo,Omolola,Omo ni ola,Omoni’yi
Omo’leye, Omolabake, Omolabage, Omopariola
Omojowolo, Omosunbo, Omofowokade, Omofowokola
Omotoriola, Omorinsola, Omorinsoye, Omobobola, Omoyosola
Omoboboye, Omoyosade,Omoyosoye, Omodapomola, Omodapomoye
Omoboriola, Omoboriola,Omotanshe,Omotanoshi, omo ju oun gbogbo lo,
Aakun dabo ore wa toju omo re nitori awon ni Ojo ola re, gbogbo Eni ti o ti bi ko ni yan ku
Agan ti ko ti bi,yio fi owo Osun pa omo lara, a ti se odun ajodun awon ewe ti odun yii,
K’edumare je ki a tun se opolopo re lori eepe tomotomo….

ASE, EDUMARE

~Asoju Omo Yoruba Atata.

Orin, Owe ati Ewi !

$
0
0

ORIN :
” Ododo-Eye mi, ko ma re danu ..
Ko maa re danu, Loju aye mi..
Ile nimo ko o, Oko nimo ra..
Omo,Omo l’adele o…
……
OWE :
* Agba waa bura bewe o ba se-o ri.
* Omo Ta o ko, Ni yoo gbe’le taa ko ta..
* Oromodire nii D’akuko
….
EWI :
Omo Lere aye
Omo N’iyun
Omo N’ide..
Omo L’ade-Ori
Omo N’ileke orun.
Panboto-Riboto..
K’ori je n R’omo gbe jo..
Tori won Lolomo lo laye..
Eni Omo sin , Lo Bimo..
Eni Bimo Tiko N’iwa..
Alai-ribi sanju iru won lo..
Omo temi ko..
Omo Elomii no..
Omo poo-bi-osan bo
Baba Obo Langido….
………
Ododo-Eye gbogbo wa konii re danu lase
Eledua

Lati owo Yinus Abiodun Wayio MC

Foto: Ara Kenge !

$
0
0

E bami kira fun Ife….gbosa, gbosa, gbosa

 

Odu merindilogun re o

Yoruba Du ‘n ka

$
0
0

Yoruba dun-un ka yoruba e komo yin o, ko tun le ko ko tun le so ede abinibi.

A~ AJA, B~ BATA, D~ DOJE, E~ EJO, E~EYE,
F~ FILA, G~ GELE……….

A B D E E F G GB H I J K L M N
1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15

O O P R S S T U W Y
16 17 18 19 20 21 22 23 24 25.

ISE IDANRA ENI WO.

KINI ORUKO YI?

17 19 23 15 14 10 13 1

2 1 19 1

1 8 17 15 15 10 19 5 7 23 15.

Viewing all 2260 articles
Browse latest View live