Akoni àti ogbóntàrigì òsèré obìnrin, tí a mò sí Mercy Johnson Okojie, tí ó fé omo oba Odi Okojie tí ó sì bí omo méta, Okúnrin kan obìnrin méjì. Mercy Johnson ti se ayeye ojó ìbí fún àkóbí rè, orúko omo báà a máa jé Purity, ó sì ti pé omo odún méfà.
Láti se ayeye náà fún omo rè, Mercy Johnson pin sí orí èro ayélujára ínsítágìràmù láti pín àwòrán omo rè tí ó rewà.
Ó ko síbè wípé:
“Odún méfà séyìn, ojó Àìkú gangan ni mo bí Purity àti wípé ó pé omo odún méfà ní òní. Farabalè…ó ti gba àyè gbogbo ènìyàn lóókan àyà mi súgbón ko séni tí ó le gba àyè re lóókan àyà mí, ìyá re ní’fé reju ayé rè lo…
Èyin òré, purity wa ti pé odún méfà lónìí.”
