Ìmú wo egbé òkùnkùn ti ó selè ní ìjoba ìbílè Obanliku ní Ìpínlè Cross River ti mú èmí eni tí won fé mú wo egbé náà lo ní ojó ketàdínl’ógbòn osù òpe odún 2018. Orúko arákùnrin náà a máa jé Miracle.
Àwon olùgbé ìlú Sankwala jí ní òwúrò ojó kejìdínl’ógbòn osù òpe, odún 2018 láti rí òkú Miracle, tí ó jé omo bíbí Bayanung, Bassang, nígbà tí ó kúkú látàrí mímú wo egbé òkúnkùn.
Olóògbé yí kú látàrí gígé oríkè-ríkè ara rè.
Àwon mérin ni owó àwon olópàá Obanliku ti te, won sì ti kó won sowósí àwon agbófinró ní Diamond Hills ní ìpínlè Calabar, tí ó sì jé wípé Ajíhìnrere wà nínú won, nígbà tí ó sì je wípé omo ègbón rè ni won fé mú wo egbé láìmò.
Wàhálà àwon ará ìlú àti ègbón ajíhìnrere yí ti jásí pàbo nígbà tí àwon olópàá tí ó mú nílé ègbón rè ti sálo.
