Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Oriki Ibeji : Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún

$
0
0

Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún.
Ẹdúnjobí

Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi

Ọ́-bẹ́-kẹ́ṣé-bẹ́-kàṣà,
Ó fẹsẹ̀ méjèèjì bẹ sílé alákìísa;
Ó salákìísà donígba aṣọ.

Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọ́mọ.

Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.

Tani o bi ibeji ko n’owo?

Orisun

The post Oriki Ibeji : Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún appeared first on Ọmọ Oódua.


Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Trending Articles