Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́

$
0
0

Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́

Bá a pẹ́ tí tí, bí ẹni rebi,bi èmi sì gùn gùn gùn bí okùn tó gùn,ikú lòpin èèyàn.
Ìjọ aláyé ti dáyé, lakásọlérí ti í ṣunkún ara a wọn, kò ṣẹ́ni tí ò níí kú, kò ṣẹ́ni tí oko baba rẹ̀ kò ní dìgbòrò.

Ìlúmọ̀ọ́ká àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí iṣẹ́ tíátà, Lere Paimọ ti sàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà, àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun.

Lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa àgbà ọ̀jẹ̀ nínú tíátà míràn, Pa Kasumu, Paimọ ní ó yẹ kí àgbàlagbà máa rí àánú gbà, láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwùjọ, kìí ṣepé èèyàn ń tọrọ.

Àgbà ọ̀jẹ̀ nínú isẹ tíátà náà ní omijé bọ́ lójú òun nígbà t’óun rí olóògbé náà gbẹ̀yìn, nitori ipo to wa.
Ó wá se àdúrà pé kí Aláwùràbí dí ẹbí tí olóògbé náà fi sílẹ̀ mú, kí Ọlọ́run forí jin òkú.

Nínú ọ̀rọ̀ tí ẹ̀, Salami sàlàyé pé ènìyàn tó ṣe é mú yangàn ni Pa Kasumu nígbà ayé rẹ̀, o si tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń tèlé òfin àti ìlànà iṣẹ́ rẹ.

Ọga Bello tẹ̀síwájú pé “Ó bani níńú jẹ́ sùgbọ́n kò sí nǹkan tí a le ṣe sí àṣẹ Ọlọ́run. Saájú àsìkò yìí ni a ti ń sàfẹ́rí Pa Kasumu nítorí ó ti tó ọdún díẹ̀ sẹ́yìn tí kò ti lè darapọ̀ mọ́ wa mọ́ láti ìgbà tí ó ti ṣe àìsàn”

“Àdúrà mi ni pé kí Ọlọ́run tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí ó sì tu àwọn ẹbí olóògbé nínú”

Toyin Adewale, Jaiye Kuti, Toyin Adegbola àti Yomi Fabiyi naa wà lára àwọn òṣère tí o ti ń ṣe elédè lẹ́yìn rẹ

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fabiyi ní “Ẹni iyì àti ẹ̀yẹ ni Pa Kasumu tí mo sì ní ìfẹ́ rẹ̀ gídí, mò ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tó ṣe nínú iṣẹ́ tíátà.”

Ní ti Toyin Adegbola, Ó ní “O dárọ Kayode Odumosu, kí Ọlọ́run dẹlẹ̀ fún, kí ó sì tẹ sí afẹ́fẹ́ rere.

Foluke Daramola- Salako ló kéde ikú Pa Kasumu lórí àtẹjiṣẹ́ instagram rẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, Kayode Odumosu kú ní ilé ìwòsàn kan ní Abeokuta lásìkò àisan ranpẹ.

Fẹ́mi Akínṣọlá


Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Trending Articles