Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Ìwúre Toni

$
0
0

Ikú tó yọ lóòré ńkọ́ 
Àrùn tó yọ lóòré ńkọ́ 
Ẹjọ́ tó yọ lóòré ńkọ́ 
Òfò tó yọ lóòré ńkọ́ 
Orí mí kọ̀wun, àyà mí kọ̀wun
Moti jẹ kọ̀ǹkọ̀ mo ti kọ̀

Owó,aya, ọmọ,gbogbo ire tó yọ lóòré ńkọ́ 
Orí mí gbàwun, àyà mí gbàwun
Moti jẹ Ọ̀̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà moti gbà

Mo sé ní ìwúre fún orí kọ̀ọ̀kan wa ní ojúmọ́ tòní wípé orí wa yóò kọ ibi,àyà wa yóò sì gba ire gbogbo fún wa kí ọ̀sẹ̀ yi tó parí. Àsẹ


Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Trending Articles