Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Àkóṣe Ọ̀ràngún Méjì

$
0
0

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná awerepèpè, a ó lọ̀ ọ́ kúnná dáadáa, a ó wà ṣa tí yóó gbẹ dáadáa.

Ọ̀ràngún méjì ni a ó tẹ̀ ẹ́. A ó pe Ifá sí, a ó fi ṣín gbẹ́rẹ́ la orí já.

A ó wà á fi ẹbu Ifá náà rá àwọn ojú gbẹ́rẹ́ yẹn. A ó wà á mú ìgbín tó gbónu kan (ìgbín apinnu), a ó fi ọgbọ́n àti sùúrù ja ní ìdí (torí wípé kò gbọdọ̀ kú o), a ó ro omi rẹ̀ sí ojú àwọn gbẹ́rẹ́ náà délẹ̀.

A ó wà á lọ ṣọ ìgbín náà sí oríta mẹ́ta tàbí ìdí Èṣù lójú òde. Ìgbín náà yóò rìn lọ fún ara rẹ̀ ni o!

*Pàrà tí a bá ti kán ìdí ìgbín yẹn, ni a ó má ro ó omi rẹ̀ ṣí ojú àwọn gbẹ́rẹ́ yẹn o. A ó gbọdọ̀ kọ́kọ́ ro ó ṣí inú ibi kankan tẹ́lẹ̀ o!

Ọba Adáni-dáni ni à pé Òrìṣà Ńlá
Ọba Abùyàndà ni à pé Orí ẹni
Ọba Atúnnidá ni à pé Ọ̀rúnmìlà
Ọba Alárànṣe ẹ̀dá ni à pé Olódùmarè
Bí Ọba Adáni-dáni bá dáni tán

Ọba Abùyàndà níí bu ènìyàn dá
Bí Ọba Abùyàndà bá bù ènìyàn dá tán
Ọba Atúnnidá níí tún ni dá sí rere
Ọba Atúnnidá wá tún èmi lámọrín dá sí rere lónìí
Kí n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ́wọ́

Ọ̀ràngún méjèèjì wá lọ sí òde ọ̀run
Kí o wá lọ rèé bá mi di ẹrù tèmi kó gún gẹ́gẹ́
Kí gbogbo Ire tí mo bá ní
Kó mọ́ le lọ mọ́
Șawerepèpè ni kí ẹ pe Ire tèmi wá fún mi lónìí

Inú ìgbín ni omi tí Olódùmarè bá pọn fún ìgbín gbé
Kí gbogbo ohun rere tí mo ní
Kó mọ́ le è yingẹ
Kó mọ́ le ṣòfò mọ́ láyé

Ire ni o!

– Òfún Méjì (Èjì Ọ̀ràngún)

Olúwo Ifákòleèpin


Viewing all articles
Browse latest Browse all 2260

Trending Articles