Quantcast
Channel: Art Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all 2260 articles
Browse latest View live

E wa wo ise opolo to fakiki

$
0
0

Ise awon asaraloge ni ki won tunrase. Sugbon nigba mi-in, won tun le baraje. Sebi bise ba se gba ni won se n se e. Ise opolo ni ise tiata, awon onitiata ni won se ise opolo.  Foto: eni ti acid da si lara ninu ere

The post E wa wo ise opolo to fakiki appeared first on Ọmọ Oódua.


Ooni tuntun wo ilu Ile-Ife tilu-tifon

Erin jade lenu Ajimobi leyin to feyin Ladoja janle nile ejo

Check out STUNNING Moscow Metro stations that look like Museum 

$
0
0


Moscow’s stunning underground network looks like a museum. Who needs a museum when you have a metro by the way ?

For many years it was prohibited to take pictures and now with the commuter rush it is impossible to get shots. But if you think Moscow metro is all style and glitter – you would be wrong. It is worlds most efficient public transport network. It is world’s most affordable too. It is grand, traditional, artistic, efficient, affordable and modern. Moscow Metro has the best free underground wifi anywhere on earth.
See more stunning photos bellow.

The post Check out STUNNING Moscow Metro stations that look like Museum  appeared first on Ọmọ Oódua.

Awada Kerikeri: Awon ole meji ti won lo fo banki

$
0
0
Awon ole meji ja ilekun banki kan loru ojo kan, won si n si awon seefu wo. Ninu akoko, yugooti bi i meloo kan ni won ri nibo, kò s’ówó. Won to yugooti naa wo, o ti kan lenu.

Won sikeji wo. Yugooti ni won tun ri nibe, won tun wo, won si ri wi pe, iyen daa lenu die. Sugbon ko tun s’owo nibe.

Won tun siketa, yugooti naa lo wa nibe.

Okan ninu won koju sikeji re, o ni “John, ki lo de to o lo sita. Ko o lo woo boya banki la fo looto, ki o si jokoo lati gbadun yugooti eyi to dun yi.

Leyin iseju die John pada de. O ni “A o kuku sile ya, banki la wa!”

Ekeji re ni “Ki gan-an ni won ko sara patako akole re?”
“Sperm Bank ilu New York!”
Akoba gaaaafara!!!
http://www.olayemioniroyin.com/2015/10/awada-kerikeri-awon-ole-meji-ti-won-lo.html

The post Awada Kerikeri: Awon ole meji ti won lo fo banki appeared first on Ọmọ Oódua.

Foto Mercy Aigbe meje (7) to ta lenu bi ataare

$
0
0


Ti ija ba wa ni be, e je a pari kia. Awon Yoruba si bo won ni tomo eni ba daa kawi, kii se ka fi saya. Egan ni he, Mercy Aigbe ta lenu bee lodun yungbayungba.  Olayemi ti mo ba n paro, eyin naa e wo enu ile kee wo enu oko. Nnkan ju nnkna lo joo.

The post Foto Mercy Aigbe meje (7) to ta lenu bi ataare appeared first on Ọmọ Oódua.

Ile ise Ologun seleri owo tabua fun eni to ba ri Boko Haram

$
0
0

Olayemi Olatilewa

 

Ile ise Ologun ile Naijiria ti se afihan foto awon ogbologbo alakatakiti esin Islam, Boko Haram bi ogorun (100) eleyii ti won on wa lati mu. Awon wonyii ni won se apejuwe won gege oloye agba  ti won on  dari Boko Haram ninu ise ijamba buruku ti won fi n da alaafia orileede Naijiria laamu.

 

Foto yii lo jade sita nigba ti won pe fun ifowosowopo ara ilu lati tete ri won mu ni ibanu pelu ero Aare Muhammadu Buhari lati fi opin si aibale okan ti Boko Haram da si orileede yii.

Oga agba awon omo ologun, Army Staff, Lt – Gen. Tukur Buratai lo gbe awon aworan yii soke niwaju awon oniroyin l’Ojoru ose to koja.

Akole awon ori foto naa ni i so wi pe ki awon ara ilu se iranlowo nipa kikan si ile ise Ologun nigbakuugba ti won ba ri eyikeyi awon eniyan to wa ninu foto naa nigboro aye.

Bakan naa ni won tun fi kun un wi pe ebun owo tabua wa fun enikeni ti o ba le ran awon lowo lati ri awon kannakori naa mu ni kiakia. Buratai ko sai fi okan awon ara ilu bale nipa abo won.

“Enikenike to ba kan si wa lati fun wa ni asiri ona ati ri awon won yii mu, a fi dayin loju wi pe a ko ni se afihan ohunkohun nipa yin fun enikeni eleyii to le se akoba tabi ijamba  fun yin. Ipamo wa ni gbogbo ohun ti e ba ba wa so ati eni ti e je yoo wa lai han sode”.

Awon nomba ibanisoro ti ile ise ologun fi sita naa ni yii: 0818155888, 08160030300 ati 07053333123.

Igbese tuntun awon omo Ologun ile yii ni awon onwoye kan ti n soro ba bayii. Won ni bi ile ise ologun se n be ara ilu fun iranlowo fihan gbangba wi pe agbara won ti fe pin tabi ko ti pin nipa igbiyanju won lati da segun Boko Haram ti won ti di egungun eja si wa lorun. Nitori wi pe, gege bi ologun, o ye ki won ni ogbon ete ti won samulo lati mu awon amokunseka naa bale.

Sugbon bi nnnkan se n lo yii dabi eni wi pe gbogbo ogbon ti won ni ni won ti lo eleyii ti ko yi ohunkohun pada ni kiakia bi a se lero

Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, odun 2002 ni iko Boko Haram gbori soke ni orileede Naijiria lati owo Mohammed Yusuf ko to wa di wi pe Abubakar Shekau n ba lo gege bi  adari. Awon kan gba wi pe egbe naa nihun se pelu egbe alakataki kan ti a mo si al-Qaeda eleyii ti Osama bin Laden da sile. Ni osu keta odun 2015 ni adari iko naa, Abubakar Shekau kede jije olooto re si egbe alakatakiti  kan ni ile Iraq ti n je ISIL.

O kere tan, awon eniyan bi milionu meji abo ni Boko Haram ti so di alainile lori nigba ti awon eniyan to le ni egberun lona ogun ti doku patapata lati owo awon iko ti won fi oruko Allah se ise ibi.

The post Ile ise Ologun seleri owo tabua fun eni to ba ri Boko Haram appeared first on Ọmọ Oódua.

“Bilionu lona bilionu owo naira ni Mimiko dabaru ni ipinle Ondo”– Alagba egbe APC

$
0
0

Olayemi Olatilewa

Alaga egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo, ogbeni Isaac Kekemeke ti fesun kan Gomina Olusegun Mimiko to je omo egbe oselu PDP nipa wi pe owo bi tirilionu kan naira (N1 trillion) ni gomina ti je mole lati nnkan bi odun mefa wa si akoko taa wayii.
Oro yii ni Siamaanu yii n so fun awon oniroyin nibi ipade idanileko kan eleyii ti awon obirin egbe oselu APC gbe kale niluu Akure. O ni Mimiko n fi ara ni awon ara ilu nipa awon owo ori kan-anpa to gbe le awon omo ipinle Ondo lori. ” Gbogbo bo se n lo lo ye wa. Gomina n fi ara ni awon eniyan nipa awon owo ori dandangbon eleyii ti won on gba lati fi di awon owo ilu ti won ti ko je seyin. Sugbon sa, o seni laanu wi pe ipinle Ondo ni ijoba eleyii to n so awon eniyan di akuse lojoojumo”.

Ogbeni Kekemeke ko sai tenu moo wi pe gbogbo eto ti to fun egbe APC lati gba ijoba ipinle naa pada lodun to n bo. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe awon eto ijoba Mimiko to pokurumusu yoo tun je anfaani fun egbe awon lati rona gba koja.

Ninu eto idibo awon omo ile igbimo asofin ipinle naa to koja, Ogbeni Kekemeke so wi pe ohun to fa ijakule fun egbe APC ko ju bi asiri ilana ati eto awon se tu si egbe oselu PDP lowo saaju ki eto idibo naa to waye.  Ati wi pe makaruru po ninu eto idibo naa eleyii to fun egbe PDP laye je.

Bakan naa lo tun fi kun-un wi pe eto ti to fun egbe APC lati dibo abele nibi ti won yoo ti mo taani yoo soju egbe naa ninu eto idibo gomina ti o waye lodun to n bo.  O si salaye wi pe eto idibo naa yoo je eyi ti o gunle ofin ati ilana egbe onigbale lai figba kan bokan ninu.

The post “Bilionu lona bilionu owo naira ni Mimiko dabaru ni ipinle Ondo” – Alagba egbe APC appeared first on Ọmọ Oódua.


Ireti Odegbami ja sofo lati di aare FIFA agbaye

$
0
0

 

OlayemiOlatilewa


Bi o tile je wi pe ajo ere boolu ile Naijiria ti n fenu so wi pe gbagbaagba ni awon wa leyin agbaboolu to gba boolu metalelogun (23) sawon ni akoko ti n gba boolu fun orileede Naijiria, sibesibe ileri atileyin naa ko si ninu akosile kankan.
Opin de ba erogba ati ala ogbontarigi agbaboolu Naijiria nigba kan ri, Segun Odegbami lati di aare ere boolu agbaye ti a mo si FIFA. Ijakule yii lo waye nigba ti awon ajo ere boolu ile Naijiria ko lati se iwe atileyin won fun un. Oru Monde to koja yii ni gbedeke ti ajo FIFA da fun awon oludije lati fi iwe atileyin yii ranse, eleyii ti yoo mu won gba won wole gege bi oludije to koju osuwon.

Gege bi  adari olupolongo ibo fun Odegbami, Ade Adeagbo se so.  O ni awon orileede bi marun-un lo ye ki awon ti gbawe atileyin yii fun Odegbami, eni ti inagije re n je Mathematical.  Sugbon o soro fun awon lati ri iwe naa gba ni awon orileede yoku lai se wi pe tile baba re gan-an ti te lowo. Sebi awon Yoruba nile lati n keso rode.

Gege bi oro Adokiye Amiesimaka, eni ti oun naa gba boolu fun ile Naijiria nigba kan naa pelu Odegbami so wi pe, ajo ere boolu Naijiria (NFF) ko figba kankan se atileyin fun Odegbami; maa jo lo mo n weyin re ni won fi oro agbaboolu Shooting Star laaarin odun 1970 si 1984 se.

“O ye ki Odegbami gan-an mo lokan re wi pe yoo soro fun-un lati ri atileyin ajo NFF gba. Eniyan ti yoo je aare FIFA agbaye ni lati je okan pataki ninu ajo ere boolu ilu re. Odegbami ko di ipo kankan mu ninu ajo NFF, ba wo lo se fe se to fe yege? Ore mi ni Odegbami, o koju osuwon lati di aare FIFA sugbon ko ta opon ayo oselu re daada”, Amiesimaka fi kun oro re bee.

Aare ere boolu Naijiria, Ogbeni Amaju Pinnick so wi pe ebi isele naa kii se lati owo ajo NFF rara bi ko se Odegbami. O ni ohun to fa idiwo fun Odegbami ni aijafafa re lori eto igbese lati di oludije fun aare FIFA agbaye.

Odegbami, eni odun metalelogota (63), ni oun ti gba fun Olorun pelu gbogbo ohun to waye. Bakan naa ni oun ti tesiwaju pelu igbe aye oun fun ojo rere to n wa niwaju oun.

The post Ireti Odegbami ja sofo lati di aare FIFA agbaye appeared first on Ọmọ Oódua.

Owo te awon omo egbe okunkun niluu Ado-Ekiti

$
0
0

Olayemi Olatilewa

Awon akekoo meji ile iwe gbogbonise ti ijoba apapo (Federal Polytechnic) to kale si Ado-Ekiti ati maanu kan ti n tu foonu se ni agbegbe naa ni won ti ko lo si iwaju ile ejo Majisireeti pelu esun wi pe won je omo egbe okunkun paraku.
Awon akekoo oloju-ba-n-deru-bomo meji naa ni Efeotor Oghenemarhe, eni odun mejilelogun (22) ati Felix Olukanmi, eni ti ojo ori re je metalelogun (23). Eni to siketa won ti oun ki i se akekoo naa ni Adebusuyi Kolawole, eni odun metadinlogbon (27) ni iwadii awon olopaa fidi re mule wi pe won je omo egbe okunkun kan ti n je Klansman Secret Cult.

Gege bi sajeninti Olasunkanmi Bankole to je olupejo se n so fun onidajo. O ni awon kannakori yii ni owo te lojo ketalelogun osu kewaa odun yii nibi won ti n sise dudu owo won. Aimoye ohun ija oloro ni won si ka mo won lowo bi aake, ibon sakabula, obe ati awon ogun abenugongo ti won fi n sohun amusagbara.

Gege bi afikun Ogbeni Bankole, o ni aimoye awon ise buruku bi ifipabanilopo, ijaagboro, ipaniyan ati ole jija to ti n waye seyin ni agbegbe naa ni iwadii fi han wi pe o lowo awon omo egbe okunkun yii ninu.

Bakan naa ni Bankole ro ile ejo lati maa gba beeli awon odaran afurasi naa rara nitori wi pe o lewu fun alaafia awujo.

Ogbeni Bankole, eni to n soro pelu ohun akin niwaju onidajo Idowu Ayenimo ko sai menu ba ohun ti iwe ofin so nipa egbe okunkun. O salaye wi pe ori kerin, abala kinni ati ori kewaa abala (a) ninu ofin Ipinle Ekiti ti won se lodun 2002 ko faaye gba egbe okunkun rara.

Nigba ti awon odaran afurasi naa so fun ile ejo wi pe awon o jebi gbogbo esun ti ile ejo fi kan awon ati wi pe ko si otito rara ninu oro olufisun awon.

Onidajo agba ti ile ejo Majisireeti, Idowu Ayenimo sun igbejo naa siwaju di  ojo karun-un osu kokanla odun yii. Leyin eyin lo ni ki won da awon odaran afurasi naa pada si ogba ewon Federal Prisons to wa ni Ado-Ekiti.

The post Owo te awon omo egbe okunkun niluu Ado-Ekiti appeared first on Ọmọ Oódua.

Won Fadi Omo Odun Meji Ya Niluu Abuja

$
0
0
Olayemi Olatilewa

Omokunrin eni odun merindinlogun (16) kan ti lo foju ba ile ejo niluu Abuja leyin asemase pelu omobirin, eni odun meji (2) kan.

Iroyin yii lo jade nigba ti olupejo, ogbeni  Adama Musa, eni ti n soju ile ise olopaa n se alaye naa niwaju ile ejo Gudu Upper Area Court to kale siluu Abuja.
Ogbeni Musa n so fun ile ejo wi pe, ogbeni Samuel Zakka ti n gbe ni abule Pegi to wa ni Kuje lo mu esun naa to ile ise olopaa wa lojo kejilelogun osu kesan-an odun yii.

Ogbeni Samuel Zakka lo salaye fun awon olopaa wi pe odaran naa tan omo re, eni odun meji lo sinu ile kan ti won on ko lowo eleyii to lo n ba omo naa se asemase nipa titi ika bo inu idi omodebirin naa.

Awon olopaa se iwadii oro yii, won mu omobirin kekere yii lo si ile iwosan fun ayewo lati mo okodoro oro. Abajade si fi ye won wi pe lotito ni asemase waye loju ara omodebirin naa.

Igba ti omokunrin odaran yii n duro niwaju ile ejo, oun to wi naa ni wi pe oun o jebi awon esun ti ile ejo fi kan-an.

Nibayii, Onidajo Umar Kagarko ti ni ki won gba beeli odaran naa pelu egberun lona ogorun owo naira(N100, 000) pelu oniduro to lokun-undi, to si tun je olugbe ilu Abuja. Nigba ti won sun igbejo naa di ojo ketadinlogun osu kejila odun 2015.

The post Won Fadi Omo Odun Meji Ya Niluu Abuja appeared first on Ọmọ Oódua.

“Eyin ni agbara ati isegun mi l’Ojoosegun”: Ipinle Oyo gba leta Ajimobi

$
0
0
Olayemi Olatilewa
Gomina ipinle Oyo, Abiola Ajimobi ti gbe sadankata fun awon eniyan ipinle Oyo fun atileyin ti won se fun un lati segun niwaju ile ejo to n risi awuyewuye eto idibo to waye lojo isegun to koja yii.

Asekagba ejo awuyewuye eto idibo gomina laaarin Ajimobi ati Rasheed Ladoja waye lose tokoja nibi ti ile ejo ti da Gomina Isiaka Abiola Ajimobi ti egbe oselu APC lare gege bi eni ti yoo ma tuko ipinle Oyo siwaju sii gege bi gomina ipinle naa.

Gomina Ajimobi ti dupe lowo awon eniyan ipinle Oyo fun atileyin ti won se fun un. O ni eleyii n se afihan ijoba awon eniyan looto. Ninu oro re lo wi pe, “isegun to waye lojo Isegun fidi re mule looto wi pe ijoba awaarawa ti rese wale. Awon eniyan ipinle Oyo ni agbara mi, awon si ni isegun mi. Mo si fi n da won loju wi pe won ko ni kabamo rara”.
Gomina si fi asiko naa ro Ladoja, oludije lati egbe oselu Accord lati fowosowopo pelu isejoba re lati gbe ipinle Oyo de ebute ogo.

Abiola Ajimobi, eni odun marunlelogota (65) ti fi igba kan je oga agba ati oludari ile ise epo robi, National Oil and Chemical Marketing Company eka ti ile ise Shell Petroleum Nigeria. Leyin bi odun merindinlogbon (26) ti Ajimobi ti n sowo epo robi lojulowo, o fi ise naa sile lodun 2002 lati gbajumo oselu sise loju paali. Odun 2003 ni ipo senato jamo lowo labe egbe oselu AD nigba ti n soju ekun Guusu Oyo.

Odun 2007 ni igba akoko ti Ajimobi yoo du ipo gomina labe egbe oselu ANPP leyin to pari ipo re gege bi senato sugbon ti ko rowo mu ninu eto idibo odun naa.

Ajimobi tun gbiyanju pada lodun 2011 labe egbe oselu ACN, eleyii ti ipo naa si ja mo o lowo. Akotun tun ni eto idibo odun 2015 je fun gomina Ajimobi, nigba ti awon eniyan ipinle Oyo tun pada dibo yan an sipo gomina fun igba keji labe egbe oselu APC. Iyansipo eleekeji re yii je igba akoko ti ipinle Oyo yoo ma yan eniyan si ipo gomina fun igba keji lera won.

The post “Eyin ni agbara ati isegun mi l’Ojoosegun”: Ipinle Oyo gba leta Ajimobi appeared first on Ọmọ Oódua.

Won o je ki Saraki o rona gba leyin to fun awon minisita Buhari lona lo

$
0
0

Olayemi Olatilewa

Ile ejo kotemilorun to kale siluu Abuja ti da esun aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki nu patapata. Ninu esun ti Saraki gbe lo si ile ejo, ibe ni Saraki ti n ro ile ejo lati pase jokoo-jee fun  Code of Conduct Tribunal (CCT) latari awuyewuye ti won gbe dide. Bakan naa lo n wi pe ki ile ejo naa da gbogbo esun ti tiribuna gbe kaa laya nu sinu omi okun agbadagbudu. Sugbon sa, kaka ki ile ejo se ohun ti saraki n pe fun, iwe ofin ni ile ejo si ti won si kaa seti gbogbo mutumuwa. Won ni Code of Conduct Bureau ni ase labe ofin lati gbe enikeni lo si ile ejo tiribuna nigba to ba ye fun won lati se bee ninu ise won.

 

Saraki ni won fi esun metala kan eleyii to dale aisododo nipa ijewo dukia eni ati awon iwa jegudujera ni awon akoko to je gomina ipinle Kwara. Nibayii, ile ejo to gaju niluu Abuja ti pase fun Code of Conduct Tribunal (CCT) lati maa ba awon esun metala ti won fi kan Bukola saraki lo lai si idiwo tabi idina kankan.

Iroyin tuntun yii lo jade lojo Eti to koja yii leyin ti Saraki ati awon senato yoku fi ontelu lu awon minisita Buhari, paapa julo, Rotimi Amaechi ti awon kan ti ni ko ni yege.

Ti e ko ba gbagbe, ojo karun-un ati ojo kefa osu kokanla odun ta a wa yii ni ile ejo tiribuna yoo tun maa pada jokoo lati ye Saraki wo bi igba ti tisa ba n gbon ise akekoo wo yebeyebe.

Lori esun jegudujera kan naa, ile ise ti n risi iwa idaran niluu London, National Crime Agency [NCA] si n ba iwadii won lo ni rebutu nipa minisita epo robi ile Naijiria nigba kan, Arabinrin Diezani Alison-Madueke lori awon esun jegudujera ti won fi kan-an.

Bi o tile je wi pe awon agbofinro ilu London ti pada tu Madueke sile ko maa lo sile, sugbon gbogbo iwe irinna re pata ni won ti gba lowo re. Eleyii ti ko fun lanfaani lati tirafu jade niluu London titi ti gbogbo iwadii ti won se yoo fi kesejari.

Nibi ti Madueke, obirin akoko ti o je aare egbe awon orileede ti won ti n fo epo-robi lagbaye, Organization of the Petroleum Exporting Countries (OPEC), ti n ronu kini o le je abajade iwadii awon olopaa ilu London, Abba Moro o loju orun mo pelu bi Aare Buhari se siwe iranti kan-an.

Boya eyin gbagbe, losu keta odun 2014, awon eniyan bi ogun, awon odo, ni won doloogbe nibi won ti n lakaka lati rise gba ni eka ile ise ijoba apapo to n risi wiwole-wode, Nigerian Immigration Service.

Abba Moro lo je minisita feto abenu nigba naa, to si je eni  ti oro naa kan gbongbon, ni awon ara ilu pe fun idaduro re lenu ise. Sugbon aare to wa nipo nigba naa, Goodluck Jonathan, foju fo asise re da.

Asiri to tun tu nigba naa ni wi pe won fi eto igbanisise naa kowo je eleyii ti won ni kan dapada sugbon ti won ko lati se bee.

Awon Yoruba bo, won ni iyan ogun odun a maa jo ni lowo felifeli.

The post Won o je ki Saraki o rona gba leyin to fun awon minisita Buhari lona lo appeared first on Ọmọ Oódua.

Niluu Ilorin: “Awon osise mefa ti ku, awon kan wa nile iwosan”- Akowe egbe osise

$
0
0

Awon osise ajo olomi ti ipinle Kwara tu jade lojo Isegun to koja yii niluu Ilorin nigba ti won fi ehonu won han nipa owo osu won eleyii ti ijoba ipinle naa ko lati san lati inu osu keje seyin.

Olayemi Olatilewa

Yato si owo osu won, awon owo ajemonu kan naa tun wa lati ibere odun yii ti a gbo wi pe awon osise naa n beere lowo ijoba eleyii to je wi pe bakan naa lomo se sori pelu owo osu ti won o ri gba. Eleyii to tun se eleeketa iru e ni awon osise to ye ki won ti ni igbega lati inu odun 2012 sugbon ti igbega naa ko waye.

 

Awon osise ajo olomi ipinle naa ni won gbarajo labe egbe kan ti nje Amalgamated Union of Public Corporations, Civil Service Technical and Recreational Services Employees (AUPCTRE), eleyii to je ti eka ajo olomi ti ipinle Kwara.

Awon osise yii ni won gbegi dina geeti abawole to wa leka ile ise ijoba naa nigba ti won fi ehonu won han eleyii to waye fun aimoye wakati.

Nibi ifehonu han naa ti n waye ni ati ri awon osise kan ti won gbe orisiirisii akole dani eleyii ti die nibe wi pe: “E san owo osu wa o”, E fun wa leto wa”, E ma foju gongosu wo wa, awa o go o”; “Ti eyin ba ni e ko ni sanwo, awa gan-an o ni sise”.

Gege bi olori egbe osise eka ti ajo olomi ipinle Kwara, Ogbeni  Murtala se so. “Aimoye leta ni ati ko si awon alase pelu ijoba sugbon to je wi pe ibi pelebe naa ni awon abebe ti a n ju soke naa fin in lele nigbogbo igba. Awa osise ti gbiyanju oun ti a mo, igba ti won sun wa kangiri la tu jade”.

Gege bi oro Ogbeni Murtala, o ni ki i se wi pe idunnu awon lo je bi awon se duro sinu oorun lai lounje ninu, sugbon ni kete ti ijoba ba ti dawon lohun awon nnkan ti awon beere fun dandan ni ki awon pada senu ise lai fi akoko sofo.

Akowe egbe osise, Ogbeni Saliu Sulaiman naa ko sai so ero tie naa fun awon oniroyin. O ni isoro ti awon ni ni wi pe ijoba o ka won kun rara.

A tile gbo wi pe awon osise yii fun ijoba ipinle naa ni gbedeke ojo merinla lati dahun awon ibeere won saaju ki ifehonuhan naa to waye. Sugbon ojo merinla naa ti koja eleyii to fa bi gbogbo osise naa se tu yaaya soju popona bi ero Mecca.

Gege bi afikun oro enu akowe naa, o ni awon osise bi mefa ni won ti padanu emi won bayii nigba ti awon kan wa nile iwosan latari wi pe won ko ri owo toju ara won botito ati botiye.

“Pupo ninu awon osise ajo olomi lo je wi pe ese ni won rin wa sibi ise nijoojumo latari wi pe ko sowo lapo won ti won le fi wo moto akero. Bakan naa ni won ti le awon kan kuro nile latari wi pe won o ri owo ile san fun awon onile won”.

Leyin isele to waye yii  ni oluranlowo agba fun gomina ipinle Kwara nipa eto iroyin, Dr Muyideen Akorede fida awon oniroyin loju wi pe ijoba yoo sa gbogbo ipa ati agbara re lati pase ohun ti awon osise naa n beere fun, ti alaafia yoo si pada joba.

The post Niluu Ilorin: “Awon osise mefa ti ku, awon kan wa nile iwosan”- Akowe egbe osise appeared first on Ọmọ Oódua.

Awon olopaa ti mu omo yahoo-yahoo niluu Ogbomoso

$
0
0

OlayemiOlatilewa

Owo awon olopaa kogberegbe ti ipinle Oyo ti te onijibiti ori ero ayelujara, Babatunde Fatai niluu Ogbomoso. Tunde to je omo asese jade ileewe Ladoke Akintola University of Technology, eleyii to kale siluu Ogbomosho to wa nipinle Oyo ni won ti mu fun esun orisiirisii to ni i se pelu ole jija ati jibiti  lori ero intaneeti ti won pe ni “yahoo-yahoo”.

 

Tunde to ni oun ti foju bale ejo ri lori esun idigunjale sugbon ti ori pada ko oun yo ni orisiirisii ona ni oun gba lu jibiti lori ero komputa. O ni nigba mi-in, oun le sebi eni ti n wa ololufe lori ero ayelujara, e ni ba ko si oun lowo je gbese. Igba mi-in si ni yii, inu owo ti won ko si banki ni oun yoo fi ona alumonkoroyi fa lo bi igba ti eniyan ba fi owo re aso lori waya.

Awon ohun ti won ka mo Tunde lowo ni akoko ti owo palanba re segi ni milionu meji ati egberun lona irinwo owo naira ile Naijiria (N2.4M), Honda CRV eleyii ti nomba re je KWL 280 CN, oko Nissan Altima eleyii ti nomba re je KJA 963 CA, oko Ford saloon oni nomba  KRD 837 DQ pelu Toyota Camry saloon ti nomba tie je LSR 418 DJ.

Igba ti kondo olopaa dun latari Tunde, ti awon olopaa kogberegbe gbe ibon sagila sibi gogongo orun re, gbogbo ohun ti won ko bi i pata lo bere si ni ka boroboro bi ero ilogi.

“O ti pe ti mo ti n se ise yii, mi o tile le ranti iye owo ti mo ti ri nidi re. E ri sir, ati jale lori intaneeti ko yisi rara o. O gba opolopo suuru. Igba mi-in, ori ikanni ti won ti n yan ore ni maa wa. Ti n si maa wa okunrin tabi obirin ti mo le denu ife ko. Ti mo ba ti ri won de mole, ohun to kan ni lati ri daju wi pe won subu sinu agbami ife mi nipa tite awon oro aladidun ranse si won ati awon ewi ife to ki. Koda, mo tun maa n pe won ta a jo soro daada lori foonu. Leyin eyi ni i maa bere si ni gba owo dollar ti n si maa fi sara rindin”.

Ko tan si be o, Tunde ti a gbo wi pe o un mura lati lo fun eto isinru ilu ti a mo si agunbaniro tun un tesiwaju ninu alaye re. Sebi iya ko toya ni omode ni ko ni daa feni to na un.

“Se e n gbo mi sir? Igba mi-in mo maa fi email adamodi ranse si awon onibara banki bi eni wi pe lati owo banki ni awon leta naa ti wa. Leyin ti mo ba ti gba pin nomba won ati nomba akaunti won ni maa wa lo ogbon alumonkoroyi yahoo-yahoo lati fa gbogbo owo won kuro lowo kan.

Iru owo bayii, mo le ko lati inu banki won ki n fi ranse si okan ninu awon ololufe mi to wa niluu okeere. Eni naa ni yoo wa pada fi ranse simi pada siluu Naijiria nibi”.

Ile ise olopaa ipinle Oyo ni o seni laanu wi pe pupo awon odo iwoyii ni won ri ise ole jija lori ero ayelujara gege bi ona kan pataki lati di eniyan nla lawujo. Won ni ko ba dara ti won ba n lo ogbon ati imo won fun awon nnkan mi-in to se e mu yangan lori intaneeti yato si yahoo-yahoo. Won tun fi kun un wi pe Tunde yoo ma foju bale ejo laipe fun ijiya to to labe ofin ile Naijiria.

The post Awon olopaa ti mu omo yahoo-yahoo niluu Ogbomoso appeared first on Ọmọ Oódua.


Iwon ese bata kan pere: E kaabo sinu osu tuntun

$
0
0

#Ogulutu #4

Eyin eniyan mi, n maa ki yin kaabo sinu osu tuntun pelu itan Ogbeni Darby omo ilu Amerika to ti n tawo-tase ninu mi fun igba pipe. Itan aroko ko, bee si ni mi o ni fe ki e fi oju sinima agbelewo wo o. Lai moye odun seyin, Darby nife si ise iwakusa.

Leyin iwadii ati ifinmu finle re, o to ipase goolu lo si awon agbegbe kan ninu igbo kijikiji. O ko oko atada dani, bee lo bere si ni gbele. Igba to gbe de aye kan, o fura wi pe goolu mbe ni ogangan ile to n gbe fun ayewo.

Sugbon oro naa koja ohun to le fi oko atada wu jade. O pada sile lo ba awon eniyan re, o salaye wi pe ohun ti sewari ibi ti eniyan ti le ri goolu wa jade. Won lo yawo ra awon moto agbele ati awon irinse iwakusa, eleyii ti won yoo lo lati fi wa awon goolu naa jade.

Akiyesi Darby ko tase rara nigba ti won de ori ile naa, won ri goolu wa jade. Iwonba eyi ti won ri ti san gbogbo gbese ti won je sorun. Darby pinnu lokan re wi pe awon goolu ti awon ba tun ri wa jade lati akoko yii lo ni yoo je ere ajemonu f’awon naa.

Subon leyin eyi, gbogbo ile ti won gbe, won o ri goolu kankan mo. Won gbele-gbele, won ko ri ohun to jo ohun ti won wa. Won tun gbiyanju bi eni wi pe goolu naa si n be nisale, pabo naa ni gbogbo re jasi.

O su Darby, o ko gbogbo irinse ti won ra ta, o si gbale lo. Okunrin to ra awon irinse naa gba ibi ti won ti sise pati lo. Igba to de be, o pe awon onimo nipa alumooni ile lati wa se ayewo ile naa boya ohun gidi kan si tun seku nibe.

Igba ti won yoo se ayewo ile naa, won ri wi pe iwon ese bata kan pere loku ti won yoo fi kan obitibiti goolu ogidi alainiye. Okunrin yii lo jifa naa, o ko aimoye goolu alailonka, o si dibe di olowo tabua.

Opolopo awon eniyan ni irewesi ti deba ti won si ti pada ninu igbiyanju won bi odun se n pari lo. Ti e ba pada, elomii ni o ko yin nifa.  Iwon ese bata kan pere lo ku fun yin lati debi ti goolu yin wa. E mu okan yin le, e ma so igbagbo yin nu.

Awon kan le maa wi pe odun ti fe e tan tabi ki won tile ni odun ti pari. Mo fi dayin loju wi pe ireti si wa wi pe owo yin si le ba ohun te n foju sun. E ma se je ki ohun to n sele ni ayika yin bu omi tutu si yin lokan. E ma se je ki ijakule dayin pada sile. E ma kari bonu, e ma so wi pe o ti pari. Ko ti i pari, ese bata kan pere loku fun yin lati debi ti e n lo.

Ohun to n sele lonii ko nihun se pelu ohun ti o sele lola. Awon nnkan ti ko seese fun yin lati nnkan bi osu mewaa seyin, le wa si imuse laaarin ojo mewaa sigba taa wa yii. Sugbon ti e ba so ireti nu, e ti so ohun gbogbo nu. Ti e ba ko lati tesiwaju, o daju wi pe e ko le debi ti goolu wa.

E le se amulo ogbon tuntun, e le paaro oju ona ti e n gba, sugbon e ri daju wi pe e ko pada sile. Awon Yoruba bo, won ni iku lonii, igbadun lola. Ohun to daju ni wi pe iku oni kii je ka jegbadun ola.

E ko lati ku sona bi eefin. E mu okan yin le bi jagunjagun. E dide nigba to ba n reyin, e sare nigba ti egun ba gun yin lese, e ma se gba ki ohunkohun fa yin seyin nitori wi pe ninu igbiyanju yin ni aseyori yin wa. E kaabo sinu osu tuntun, osu ayo, osu idunnu ati igbega.

Olayemi Olatilewa

The post Iwon ese bata kan pere: E kaabo sinu osu tuntun appeared first on Ọmọ Oódua.

“Ni Akute, awon ota ni won ba Amosun loruko je” Ijoba ipinle Ogun

$
0
0

Olayemi Olatilewa

Ile ise ijoba ipinle Ogun ti pe akiyesi awon ara ilu si iroyin eleje kan ti iwe iroyin kan gbe jade wi pe wahala wa laaarin awon oloja ti won gbe ni agbegbe Akute ati gomina ipinle Ogun, Senato Ibikunle Amosun. Iwe Iroyin to jade naa tun fi kun un wi pe atunse awon oju ona lati Akute titi to fi de Alagbole to wa ni ijoba ibile Ifo ti n lo lowo lo je ise owo awon egbe oloja eleyii ti won ni ijoba Amosun ko lati ba won dasi.

 

Gege bi atejade ti akowe agba fun ile ise ijoba ti n risi ise ode ati igbayegbadun ara ilu, Engr. Kayode Ademolake fi sita lojo Aje to koja yii se so. O salaye wi pe ohun to foju han gbangban ni wi pe ijoba ipinle Ogun ti gbe ise oju ona Sango-Ijoko-Agbole-Akute-Ojodu Abiodun, eleyii to wa lara oju ona ti won soro ba, fun awon agbase se.

Ogbeni Kayode lo je ohun ijoloju lati gbo wi pe awon kan an pa iru iro bantabatan bee wi pe kii se ijoba lo n se awon ise oju ona naa. “Ko ni dara ki a maa da idagbasoke ilu po mo oselu sise, idagbasoke ye ko je ojuse gbogbo wa ni”. Ogbeni Kayode tun soro siwaju sii…

“Bi o tile je wi pe awon ise naa fa seyin lenu ojo meta yii latari awon ojo suuru ti n ro, sibesibe eyi ko fi ibi kankan mu adiku de ba ileri ati ife gomina si awon ara ilu. Ohun to tun daju ni wi pe ijoba to wa lode yii ko ni loju orun ayafi ti o ba mu awon ileri re pata se. Pataki ibe ti mo tun gbodo fi kun ni wi pe aimoye ise lo wa lowo wa ti a n ba lo lati ri wi pe awon oju ona wa se e gba fun awon eniyan wa pelu irorun. Lara awon oju ona ti ise ti n tesiwaju ni oju ona Sango-Ijoko, Ope-Ilu, Agbado, Abule Ekun, Akute- Alagbole, Owode-Ijako eleyii towa laaarin oju ona Eko si Abeokuta, Sagamu-Ogijo, Ijebu Ode ati bee bee lo

The post “Ni Akute, awon ota ni won ba Amosun loruko je” Ijoba ipinle Ogun appeared first on Ọmọ Oódua.

Awon egbe APC ti ko lati mu ileri won se #Our5K

$
0
0

Nje e ti gbo?

Awon omo ile igbimo asofin agba l’Abuja ti won je ti omo egbe APC ti tako aba eleyii to wa nibamu pelu ileri ti Aare se lati maa san egberun marun-un owo naira (5K) fun awon odo ti ko nise lowo. Ileri yii ni aare se nigba eto iponlongo ibo. Sugbon bayii, awon omo ile igbimo asofin ti won je omo egbe APC ti da aba naa nu bi omi isanwo.

The post Awon egbe APC ti ko lati mu ileri won se #Our5K appeared first on Ọmọ Oódua.

Foto tuntun: E wo ohun ti Mikel Obi n se loju titi

Iyanu sele leyin odun meta  

$
0
0

Odun meta lo gba arakunrin yii lati yii igbe aye re pada si bo se fe. O salaye wi pe alaafia ti de ba ara oun bayii, oun le mi daada bakan naa ni oun jafafa ju ti tele lo. Eyin didun to n da oun laamu latari ara sisan asanju ti fo lo bi eye.

The post Iyanu sele leyin odun meta   appeared first on Ọmọ Oódua.

Viewing all 2260 articles
Browse latest View live